[1] Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò fi idà rẹ̀ jẹ ni ní yà idà rẹ̀ a mú bí iná tí ó tóbi tí ó sì lágbára Lefitani ejò tí ń yọ̀ tẹ̀ẹ̀rẹ̀ n nì, Lefitani ejò tí ń lọ́ bìrìkìtì; Òun yóò sì pa ẹ̀mí búburú inú Òkun náà.
[2] Ní ọjọ́ náà, “Kọrin nípa ọgbà àjàrà eléso kan.
[3] Èmi Olúwa ń bojútó o, Èmi ó bomirin ín láti ìgbàdégbà. Èmi ó ṣọ́ ọ tọ̀sán tòru kí ẹnikẹ́ni má ba à pa á lára.
[4] Inú kò bí mi. Bí ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n bá dojú ìjà kọ mí! Èmi yóò dìde sí wọn ní ogun, Èmi yóò sì dáná sun gbogbo wọn.
[5] Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, jẹ́ kí wọn wá sọ́dọ̀ mi fún ààbò; jẹ́ kí wọ́n wá àlàáfíà pẹ̀lú mi, bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí wọn wá àlàáfíà pẹ̀lú mi.”
[6] Ní ọjọ́ iwájú Jakọbu yóò ta gbòǹgbò, Israẹli yóò tanná yóò sì rudi èso rẹ̀ yóò sì kún gbogbo ayé.
[7] Ǹjẹ́ Olúwa ti lù ú gẹ́gẹ́ bí ó ti lu àwọn tí ó lù ú bolẹ̀? Ǹjẹ́ a ti pa á gẹ́gẹ́ bí a ti pa àwọn tí ó pa á?
[8] Nípa ogun jíjà àti ìjìyà ti o le ni ó fi dojúkọ ọ́ pẹ̀lú ìjì gbígbóná ni ó lé e jáde, gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn fẹ́.
[9] Nítorí èyí báyìí ni ètùtù yóò ṣe wà fún ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu, èyí ni yóò sì jẹ́ èso kíkún ti ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Nígbà tí ó bá mú kí àwọn òkúta pẹpẹ dàbí òkúta ẹfun tí a fọ́ sí wẹ́wẹ́, kì yóò sí ère Aṣerah tàbí pẹpẹ tùràrí tí yóò wà ní ìdúró.
[10] Ìlú olódi náà ti dahoro, ibùdó ìkọ̀sílẹ̀, tí a kọ̀ tì gẹ́gẹ́ bí aginjù; níbẹ̀ ni àwọn ọmọ màlúù ti ń jẹ oko níbẹ̀ ni wọn ń sùn sílẹ̀; wọn sì jẹ gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ tán.
[11] Nígbà tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ bá rọ, a ó ya wọn dànù àwọn obìnrin dé, wọ́n sì fi wọ́n dáná nítorí aláìlóye ènìyàn ni wọn jẹ́, nítorí náà ni ẹni tí ó dá wọn kì yóò ṣàánú fún wọn; bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó mọ wọn kì yóò sì fi ojúrere wò wọ́n.
[12] Ní ọjọ́ náà Olúwa yóò sì kó oore láti ìṣàn omi odo Eufurate wá títí dé Wadi ti Ejibiti, àti ìwọ, ìwọ ọmọ Israẹli, ni a ó kójọ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.
[13] Àti ní ọjọ́ náà, a ó fun fèrè ńlá kan. Gbogbo àwọn tí ń ṣègbé lọ ní Asiria àti àwọn tí ń ṣe àtìpó ní Ejibiti yóò wá sin Olúwa ní òkè mímọ́ ní Jerusalẹmu.