Listen to this chapter • 1:13
[1] Ní ọjọ́ náà ni ìwọ ó wí pé, “Èmi ó yìn ọ́, Olúwa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ò ti bínú sí mi ìbínú rẹ ti yí kúrò níbẹ̀ ìwọ sì ti tù mí nínú.
[2] Nítòótọ́ Ọlọ́run ni ìgbàlà mi, èmi yóò gbẹ́kẹ̀lé e èmi kì yóò bẹ̀rù. Olúwa, Olúwa náà ni agbára à mi àti orin ìn mi, òun ti di ìgbàlà mi.”
[3] Pẹ̀lú ayọ̀ ni ìwọ yóò máa pọn omi láti inú kànga ìgbàlà.
[4] Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò wí pé, “Fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀, jẹ́ kí ó di mí mọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ohun tí ó ti ṣe kí o sì kéde pé a ti gbé orúkọ rẹ̀ ga.
[5] Kọ orin sí Olúwa, nítorí ó ti ṣe ohun tí ó lógo, jẹ́ kí èyí di mí mọ̀ fún gbogbo ayé.
[6] Kígbe sókè kí o sì kọrin fún ayọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Sioni, nítorí títóbi ni ẹni mímọ́ kan ṣoṣo ti Israẹli láàrín yín.”
Ìwé Wòlíì Isaiah — Chapters
15:5823:5734:1441:2456:2462:5874:4284:1594:41106:28113:35121:13134:10146:22152:10163:18173:11182:01195:07201:32213:35225:01233:54244:14252:41264:03272:53286:32295:11306:57312:27323:45334:46343:43352:11364:54378:15384:13392:05406:00416:21425:14435:39447:01456:17462:58473:50485:07496:49502:58515:46523:10532:56543:46552:56562:54574:37584:19594:37605:05612:48622:47634:26642:21656:00666:27