Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 4:03

[1] Ní ọjọ́ náà ni a ó kọ orin yìí ní ilẹ̀ Juda. Àwa ní ìlú alágbára kan, Ọlọ́run fi ìgbàlà ṣe ògiri àti ààbò rẹ̀.

[2] Ṣí àwọn ìlẹ̀kùn kí àwọn olódodo orílẹ̀-èdè kí ó lè wọlé, orílẹ̀-èdè tí ó pa ìgbàgbọ́ mọ́.

[3] Ìwọ yóò pa á mọ́ ní àlàáfíà pípé ọkàn ẹni tí ó dúró ṣinṣin, nítorí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.

[4] Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa títí láé, nítorí Olúwa, Olúwa ni àpáta ayérayé náà.

[5] Ó sọ àwọn tí ó ń gbé ní òkè di onírẹ̀lẹ̀ ó rẹ ìlú agbéraga náà nílẹ̀; ó sọ ọ́ di ilẹ̀ pẹrẹsẹ ó sì sọ ọ́ sílẹ̀ nínú erùpẹ̀.

[6] Ẹsẹ̀ tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ ẹsẹ̀ aninilára n nì, ipasẹ̀ àwọn òtòṣì.

[7] Ipa ọ̀nà àwọn olódodo tẹ́jú, ìwọ tó dúró ṣinṣin, ìwọ mú ọ̀nà àwọn olódodo ṣe geere.

[8] Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, rírìn ní ọ̀nà òfin rẹ àwa dúró dè ọ́; orúkọ rẹ àti òkìkí rẹ àwọn ni ohun tí ọkàn wa ń fẹ́.

[9] Ọkàn mi ń pòùngbẹẹ̀ rẹ ní ọ̀gànjọ́ òru; ní òwúrọ̀ ni ẹ̀mí mi ń ṣàfẹ́rí rẹ. Nígbà tí ìdájọ́ rẹ bá sọ̀kalẹ̀ sórí ayé àwọn ènìyàn yóò kọ́ ìṣòdodo.

[10] Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a fi oore-ọ̀fẹ́ hàn sí àwọn ìkà wọn kò kọ́ láti sọ òdodo; kódà ní ilẹ̀ àwọn tí ó dúró ṣinṣin wọ́n tẹ̀síwájú láti máa ṣe ibi wọn kò sì ka ọláńlá Olúwa sí.

[11] Olúwa, ti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ṣùgbọ́n àwọn kò rí i. Jẹ́ kí wọ́n rí ìtara rẹ fún àwọn ènìyàn rẹ kí ojú kí ó tì wọ́n; jẹ́ kí iná tí a fi pamọ́ fún àwọn ọ̀tá rẹ jó wọn run.

[12] Olúwa, ìwọ fi àlàáfíà lélẹ̀ fún wa; ohun gbogbo tí a ti ṣe yọrí ìwọ ni ó ṣe é fún wa.

[13] Olúwa Ọlọ́run wa, àwọn olúwa mìíràn lẹ́yìn rẹ ti jẹ ọba lé wa lórí, ṣùgbọ́n orúkọ rẹ nìkan ni àwa fi ọ̀wọ̀ fún.

[14] Wọ́n ti kú báyìí, wọn ò sí láààyè mọ́; gbogbo ẹ̀mí tí ó ti kọjá lọ wọ̀nyí kò le dìde mọ́. Ìwọ jẹ́ wọ́n ní ìyà o sì sọ wọ́n di asán, ìwọ pa gbogbo ìrántí wọn rẹ́ pátápátá.

[15] Ìwọ ti mú orílẹ̀-èdè gbòòrò, Olúwa; ìwọ ti mú orílẹ̀-èdè bí sí i. Ìwọ ti gba ògo fún ara rẹ; ìwọ ti sún gbogbo àwọn ààlà ilẹ̀ sẹ́yìn.

[16] Olúwa, wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ nínú ìpọ́njú wọn; nígbà tí ìbáwí rẹ wà lára wọn, wọ́n gbàdúrà kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́.

[17] Gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó lóyún tí ó sì fẹ́rẹ̀ bímọ tí í rúnra tí ó sì ń sọkún nínú ìrora rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwa rí níwájú rẹ Olúwa.

[18] Àwa wà nínú oyún, a wà nínú ìrora, ṣùgbọ́n, afẹ́fẹ́ ni a bí lọ́mọ. Àwa kò mú ìgbàlà wá sí ilẹ̀ ayé; àwa kọ́ ni a bí àwọn ènìyàn tí ó wà láyé.

[19] Ṣùgbọ́n àwọn òkú yín yóò wà láààyè ara wọn yóò dìde. Ìwọ tí o wà nínú erùpẹ̀, dìde nílẹ̀ kí o sì ké igbe ayọ̀. Ìrì rẹ dàbí ìrì òwúrọ̀, ayé yóò bí àwọn òkú rẹ̀ lọ́mọ.

[20] Ẹ lọ, ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ wọ ìyẹ̀wù yín lọ kí ẹ sì ti àwọn ìlẹ̀kùn lẹ́yìn yín, ẹ fi ara yín pamọ́ fún ìgbà díẹ̀ títí tí ìbínú rẹ̀ yóò fi rékọjá.

[21] Kíyèsi i, Olúwa ń jáde bọ̀ láti ibùgbé rẹ̀ láti jẹ àwọn ènìyàn ilẹ̀ ayé ní ìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ayé yóò sì sọ àwọn ẹ̀jẹ̀ tí a ta sí orí rẹ̀; kì yóò sì fi àwọn tí a ti pa pamọ́ mọ́.

Ìwé Wòlíì Isaiah — Chapters