[1] Nígbà tí ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí ní pọ̀ si ní orí ilẹ̀, wọ́n sí bí àwọn ọmọbìnrin.
[2] Àwọn ọmọ Ọlọ́run rí i wí pé àwọn ọmọbìnrin ènìyàn lẹ́wà, wọ́n sì fẹ́ èyíkéyìí tí ó wù wọ́n ṣe aya.
[3] Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Èémí ìyè tí mo mí sínú ènìyàn kò ní máa gbé inú ènìyàn títí láé, nítorí ẹran-ara sá à ni òun, ọgọ́fà ọdún ni ọjọ́ rẹ̀ yóò jẹ́.”
[4] Àwọn òmíràn wà láyé ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àti lẹ́yìn ìgbà náà; nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run lọ bá àwọn ọmọbìnrin ènìyàn lòpọ̀ tí wọ́n sì bímọ fún wọn. Àwọn náà ni ó di akọni àti olókìkí ìgbà náà.
[5] Olúwa sì rí bí ìwà búburú ènìyàn ti ń gbilẹ̀ si, àti pé gbogbo èrò inú rẹ̀ kìkì ibi ni, ní ìgbà gbogbo.
[6] Inú Olúwa sì bàjẹ́ gidigidi nítorí pé ó dá ènìyàn sí ayé, ọkàn rẹ̀ sì gbọgbẹ́.
[7] Nítorí náà, Olúwa wí pé, “Èmi yóò pa ènìyàn tí mo ti dá run kúrò lórí ilẹ̀, ènìyàn àti ẹranko, àti ohun tí ń rákò, àti ẹyẹ ojú ọ̀run, nítorí inú mi bàjẹ́ pé mo ti dá wọn.”
[8] Ṣùgbọ́n, Noa rí ojúrere Olúwa.
[9] Wọ̀nyí ni ìtàn Noa. Noa nìkan ni ó jẹ́ olóòótọ́ ènìyàn àti ẹni tí ó pé ní ìgbà ayé rẹ̀, ó sì fi òtítọ́ bá Ọlọ́run rìn.
[10] Noa sì bí ọmọkùnrin mẹ́ta, Ṣemu, Hamu àti Jafeti.
[11] Ayé sì kún fún ìbàjẹ́ gidigidi ní ojú Ọlọ́run, ó sì kún fún ìwà ipá pẹ̀lú.
[12] Ọlọ́run sì rí bí ayé ti bàjẹ́ tó, nítorí àwọn ènìyàn inú ayé ti bá ara wọn jẹ́ ní gbogbo ọ̀nà wọn.
[13] Ọlọ́run sì wí fún Noa pé, “Èmi yóò pa gbogbo ènìyàn run, nítorí ilẹ̀ ayé kún fún ìwà ipá nípasẹ̀ wọn. Èmi yóò pa wọ́n run àti ayé pẹ̀lú.
[14] Nítorí náà fi igi ọ̀mọ̀ kan ọkọ̀, kí o sì yọ yàrá sí inú rẹ̀, kí o sì fi ọ̀dà ilẹ̀ rẹ́ ẹ tinú-tẹ̀yìn.
[15] Báyìí ni ìwọ yóò ṣe kan ọkọ̀ náà: Gígùn rẹ̀ ní òró yóò jẹ́ ọ̀ọ́dúnrún (300) ìgbọ̀nwọ́, ìbú rẹ̀ yóò jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́, nígbà tí gíga rẹ̀ yóò jẹ́ ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́.
[16] Ṣe òrùlé sí orí ọkọ̀ náà ní ìgbọ̀nwọ́ kan, sì ṣe ọkọ̀ náà ní alájà mẹ́ta, ipá kan ní ìsàlẹ̀, ọ̀kan ní àárín àti ọ̀kan tí ó kù ní òkè, ẹ̀gbẹ́ ni kí ó ṣe ẹnu-ọ̀nà ọkọ̀ náà sí.
[17] Èmi yóò mú ìkún omi wá sí ayé láti pa gbogbo ohun ẹlẹ́mìí run lábẹ́ ọ̀run. Gbogbo ẹ̀dá tí ó ní èémí ìyè ní inú. Gbogbo ohun tí ó wà nínú ayé yóò parun.
[18] Ṣùgbọ́n èmi ó dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ, ìwọ yóò sì wọ ọkọ̀, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú aya rẹ.
[19] Ìwọ yóò mú gbogbo ohun alààyè takọ tabo wá sí inú ọkọ̀, kí wọn le wà láààyè pẹ̀lú rẹ.
[20] Mú onírúurú àwọn ẹyẹ, ẹranko àti àwọn ohun tí ń rákò ní méjì méjì, kí a bá lè pa wọ́n mọ́ láààyè.
[21] Mú onírúurú oúnjẹ wá sínú ọkọ̀, kí o pa wọ́n mọ́ fún jíjẹ gbogbo ẹ̀yin tí ẹ wà nínú ọkọ̀ àti ènìyàn àti ẹranko.”
[22] Noa sì ṣe ohun gbogbo bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún un.