[1] Nígbà náà ni Josẹfu pàṣẹ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Di oúnjẹ kún inú àpò àwọn ọkùnrin náà tó ìwọ̀n èyí tí wọ́n le rù, kí o sì mú owó olúkúlùkù àwọn ọkùnrin náà padà sí ẹnu àpò rẹ̀.
[2] Nígbà náà ni kí o mú kọ́ọ̀bù idẹ mi sí ẹnu àpò èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn nínú wọn pẹ̀lú owó tí ó fi ra ọkà,” ó sì ṣe bí Josẹfu ti sọ.
[3] Bí ilẹ̀ ti ń mọ́, wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn padà lọ pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn.
[4] Wọn kò tí ì rìn jìnnà sí ìlú náà tí Josẹfu fi wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Lépa àwọn ọkùnrin náà, nígbà tí o bá sì bá wọn, kí o wí pé, ‘Èéṣe ti ẹ fi búburú san rere?
[5] Èyí ha kọ́ ni kọ́ọ̀bù tí olúwa mi ń lò fún ohun mímu tí ó sì tún ń fi í ṣe àyẹ̀wò? Ohun tí ẹ ṣe yìí burú púpọ̀.’ ”
[6] Nígbà tí ó sì bá wọn, o sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún wọn.
[7] Ṣùgbọ́n wọ́n dá a lóhùn pé, “Kí ló dé tí olúwa mi sọ irú nǹkan wọ̀nyí? Ká má rí i! Àwọn ìránṣẹ́ rẹ kò le ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀!
[8] A tilẹ̀ mú owó tí a rí lẹ́nu àpò wa padà tọ̀ ọ́ wá láti ilẹ̀ Kenaani. Nítorí náà èéṣe tí àwa yóò fi jí wúrà tàbí idẹ ní ilé olúwa à rẹ?
[9] Bí a bá rí i lọ́wọ́ èyíkéyìí nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ, kíkú ni yóò kú, àwọn tí ó kù yóò sì di ẹrú fún olúwa à rẹ.”
[10] Ó wí pé, “Ó dára, kí ó rí bí ẹ ti ṣe sọ. Ẹnikẹ́ni tí mo bá rí i lọ́wọ́ rẹ̀ yóò di ẹrú mi. Ẹ̀yin tí ó kù yóò sì wà láìlẹ́bi.”
[11] Olúkúlùkù wọn yára sọ àpò rẹ̀ kalẹ̀, wọ́n sì tú u.
[12] Nígbà náà ni ìránṣẹ́ náà bẹ̀rẹ̀ sí ní í wá a, bẹ̀rẹ̀ láti orí ẹ̀gbọ́n títí lọ sórí àbúrò pátápátá. Ó sì rí kọ́ọ̀bù náà nínú àpò ti Benjamini.
[13] Nígbà tí wọ́n rí èyí, wọ́n fa aṣọ wọn ya, wọ́n sì banújẹ́ gidigidi, wọn tún ẹrù wọn dì sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, wọ́n sì padà sí inú ìlú.
[14] Josẹfu sì wà nínú ilé nígbà tí Juda àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wọlé wá. Gbogbo wọn sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀.
[15] Josẹfu wí fún wọn pé, “Èwo ni èyí tí ẹ ṣe yìí? Ṣe ẹ kò mọ pé, ènìyàn bí èmi le è rí ìdí nǹkan nípa ṣíṣe àyẹ̀wò?”
[16] Juda dáhùn pé, “Kí ni à bá sọ fún olúwa mi? Báwo ni a ṣe lè wẹ ara wa mọ́? Ọlọ́run ti tú àṣírí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, a ti di ẹrú olúwa à mi báyìí àwa fúnra wa àti ẹni náà tí a rí kọ́ọ̀bù lọ́wọ́ rẹ̀.”
[17] Ṣùgbọ́n Josẹfu dáhùn pé, “Ká má rí i pé mo ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀! Ẹni tí a bá kọ́ọ̀bù mi lọ́wọ́ rẹ̀ nìkan ni yóò di ẹrú mi, ẹ̀yin tí ó kù, ẹ máa lọ sọ́dọ̀ baba yín ní àlàáfíà.”
[18] Nígbà náà ni Juda súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Jọ̀wọ́ olúwa mi, jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ kí ó sọ ọ̀rọ̀ kan fún olúwa mi, má ṣe bínú sí ìránṣẹ́ rẹ bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ pẹ̀lú láṣẹ bí i ti Farao.
[19] Olúwa mi béèrè lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ǹjẹ́ ó ní baba tàbí arákùnrin?’
[20] Àwa sì wí fún olúwa mi pé, ‘A ni baba tí ó ti darúgbó, ọmọkùnrin kan sì wà pẹ̀lú tí a bí fún un ní ọjọ́ ogbó rẹ̀. Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan sì ni ó kù nínú àwọn ọmọ ìyá rẹ̀, baba rẹ̀ sì fẹ́ràn án rẹ̀.’
[21] “Nígbà náà ni ó sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ẹ mu un tọ̀ mí wá kí n le fojú ara mi rí i.’
[22] A sì sọ fún olúwa à mi pé, ‘Ọmọkùnrin náà kò le è fi baba rẹ̀ sílẹ̀, bí ó bá dán an wò baba rẹ̀ yóò kú.’
[23] Ṣùgbọ́n ìwọ wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ẹ má ṣe padà tọ̀ mí wá àyàfi bí àbíkẹ́yìn yín bá bá yín wá.’
[24] Nígbà tí a padà lọ sọ́dọ̀ baba wa, tí í ṣe ìránṣẹ́ rẹ, a sọ ohun tí olúwa à mi wí fún un.
[25] “Nígbà náà ni baba wa wí pé, ‘Ẹ padà lọ láti lọ ra oúnjẹ díẹ̀ wá.’
[26] Ṣùgbọ́n a wí pe, ‘Àwa kò le è padà lọ, àyàfi bí àbúrò wa pátápátá yóò bá bá wa lọ. A kò le è rí ojú ọkùnrin náà àyàfi tí àbúrò wa bá lọ pẹ̀lú wa.’
[27] “Baba mi, ìránṣẹ́ rẹ wí fún wa pé, ‘Ẹ mọ̀ pé ìyàwó mi bí ọmọkùnrin méjì fún mi.
[28] Ọ̀kan nínú wọn lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, mo sì wí pé, “Dájúdájú a ti fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.” N kò sì tí ì ri láti ọjọ́ náà.
[29] Tí ẹ bá tún mú èyí lọ, kúrò lọ́dọ̀ mi, tí ohunkóhun bá ṣe é, ìbànújẹ́ ni ẹ ó fi mú ewú orí mi lọ sí ipò òkú.’
[30] “Nítorí náà, bí a bá padà tọ baba wa lọ láìsí ọmọ náà pẹ̀lú wa nígbà tí a mọ̀ pé, ọmọ náà ni ẹ̀mí baba wa.
[31] Tí ó bá ri pé ọmọkùnrin náà kò wá pẹ̀lú wa, yóò kùú. Àwọn ìránṣẹ́ rẹ yóò wá mú baba wa tòun ti ewú orí lọ sí ipò òkú ní ìbànújẹ́.
[32] Ìránṣẹ́ rẹ ló ṣe onídùúró fún ààbò ọmọ náà lọ́dọ̀ baba mi. Mo wí pé, ‘Bí n kò bá mú un padà tọ̀ ọ́ wá, baba mi, èmi ó ru ẹ̀bi rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé mi!’
[33] “Nítorí náà, jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ kí ó dúró ní ìhín lọ́dọ̀ olúwa à mi bí ẹrú dípò ọmọ náà. Kí ọmọ náà bá àwọn arákùnrin rẹ̀ padà.
[34] Báwo ni mo ṣe lè padà tọ baba mi lọ láì bá ṣe pé ọmọ náà wà pẹ̀lú mi? Rárá, èmi kò fẹ́ kí n rí ìbànújẹ́ tí yóò dé bá baba mi.”