[1] Èyí ni ìran àwọn ọmọ Noa: Ṣemu, Hamu àti Jafeti, tí àwọn náà sì bí ọmọ lẹ́yìn ìkún omi.
[2] Àwọn ọmọ Jafeti ni: Gomeri, Magogu, Madai, Jafani, Tubali, Meṣeki àti Tirasi.
[3] Àwọn ọmọ Gomeri ni: Aṣkenasi, Rifati àti Togarma.
[4] Àwọn ọmọ Jafani ni: Eliṣa, Tarṣiṣi, Kittimu, àti Dodanimu.
[5] (Láti ọ̀dọ̀ àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ń gbé agbègbè tí omi wà ti tàn ká agbègbè wọn, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, ìdílé wọn ní orílẹ̀-èdè wọn, olúkúlùkù pẹ̀lú èdè tirẹ̀).
[6] Àwọn ọmọ Hamu ni: Kuṣi, Ejibiti, Puti àti Kenaani.
[7] Àwọn ọmọ Kuṣi ni: Seba, Hafila, Sabta, Raama, àti Sabteka. Àwọn ọmọ Raama ni: Ṣeba àti Dedani.
[8] Kuṣi sì bí Nimrodu, ẹni tí ó di alágbára jagunjagun ní ayé.
[9] Ó sì jẹ́ ògbójú ọdẹ níwájú Olúwa; nítorí náà ni a ṣe ń wí pé, “Bí Nimrodu, ògbójú ọdẹ níwájú Olúwa.”
[10] Ìjọba rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni Babeli, Ereki, Akkadi, Kalne, gbogbo wọn wà ní ilẹ̀ Ṣinari.
[11] Láti ilẹ̀ náà ni ó ti lọ sí Asiria, níbi tí ó ti tẹ ìlú Ninefe, Rehoboti àti Kala,
[12] àti Resini, tí ó wà ní àárín Ninefe àti Kala, tí ó jẹ́ ìlú olókìkí.
[13] Ejibiti sì bí Ludimu, Anamimu, Lehabimu, Naftuhimu.
[14] Patrusimu, Kasluhimu (láti ọ̀dọ̀ ẹni tí àwọn ará Filistini ti wá) àti àwọn ará Kaftorimu.
[15] Kenaani sì bí Sidoni àkọ́bí rẹ̀, àti Heti.
[16] Àti àwọn ará Jebusi, àti àwọn ará Amori, àti àwọn ará Girgaṣi,
[17] àti àwọn ará Hifi, àti àwọn ará Arki, àti àwọn ará Sini,
[18] àti àwọn ará Arfadi, àti àwọn ará Semari, àti àwọn ará Hamati. Lẹ́yìn èyí ni àwọn ẹ̀yà Kenaani tànkálẹ̀.
[19] Ààlà ilẹ̀ àwọn ará Kenaani sì dé Sidoni, lọ sí Gerari títí dé Gasa, lọ sí Sodomu, Gomorra, Adma àti Seboimu, títí dé Laṣa.
[20] Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Hamu, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, àti èdè wọn, ní ìpínlẹ̀ wọn àti ní orílẹ̀-èdè wọn.
[21] A bí àwọn ọmọ fún Ṣemu tí Jafeti jẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin: Ṣemu sì ni baba gbogbo àwọn ọmọ Eberi.
[22] Àwọn ọmọ Ṣemu ni: Elamu, Aṣuri, Arfakṣadi, Ludi àti Aramu.
[23] Àwọn ọmọ Aramu ni: Usi, Huli, Geteri àti Meṣeki.
[24] Arfakṣadi sì bí Ṣela, Ṣela sì bí Eberi.
[25] Eberi sì bí ọmọ méjì: ọ̀kan ń jẹ́ Pelegi, nítorí ní ìgbà ọjọ́ rẹ̀ ni ilẹ̀ ya; orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Joktani.
[26] Joktani sì bí Almodadi, Ṣelefi, Hasarmafeti, Jera.
[27] Hadoramu, Usali, Dikla,
[28] Obali, Abimaeli, Ṣeba.
[29] Ofiri, Hafila àti Jobabu. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Joktani.
[30] Agbègbè ibi tí wọn ń gbé bẹ̀rẹ̀ láti Meṣa títí dé Sefari, ní àwọn ilẹ̀ tó kún fún òkè ní ìlà-oòrùn.
[31] Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà ọmọ Ṣemu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, ní èdè wọn, ní ilẹ̀ wọn àti ní orílẹ̀-èdè wọn.
[32] Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà ọmọ Noa gẹ́gẹ́ bí ìran wọn, ní orílẹ̀-èdè wọn. Ní ipasẹ̀ wọn ni àwọn ènìyàn ti tàn ká ilẹ̀ ayé lẹ́yìn ìkún omi.