[1] Dafidi sì tún kó gbogbo àwọn akọni ọkùnrin ní Israẹli jọ, wọ́n sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (30,000).
[2] Dafidi sì dìde, ó sì lọ àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ń bẹ́ lọ́dọ̀ rẹ́, láti Baalahi ní Juda wá, láti mú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run tí ibẹ̀ wá, èyí tí a ń pe orúkọ rẹ̀ ní orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí ó jókòó láàrín àwọn kérúbù.
[3] Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run náà gun kẹ̀kẹ́ tuntun kan, wọ́n sì mú un láti ilé Abinadabu wá, èyí tí ó wà ní Gibeah: Ussa àti Ahio, àwọn ọmọ Abinadabu sì ń dá kẹ̀kẹ́ tuntun náà.
[4] Wọ́n sì mú un láti ilé Abinadabu jáde wá, tí ó wà ní Gibeah, pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, Ahio sì ń rìn níwájú àpótí ẹ̀rí náà.
[5] Dafidi àti gbogbo ilé Israẹli sì ṣiré níwájú Olúwa lára gbogbo onírúurú ohun èlò orin tí a fi igi arère ṣe àti lára ìlù haapu, ní ara tambori, sisitirumu àti lára kimbali.
[6] Nígbà tí wọ́n dé sí ilẹ̀ ìpakà Nakoni, Ussa sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, ó sì dìímú, nítorí tí màlúù kọsẹ̀.
[7] Ìbínú Olúwa sì ru sí Ussa; Ọlọ́run sì pa á níbẹ̀ nítorí ìṣísẹ̀ rẹ̀; níbẹ̀ ni ó sì kù ní ẹ̀bá àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run.
[8] Inú Dafidi sì bàjẹ́ nítorí tí Olúwa gé Ussa kúrò, ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Peresi-Usa títí ó fi di òní yìí.
[9] Dafidi sì bẹ̀rù Olúwa ní ọjọ́ náà, ó sì wí pé, “Àpótí ẹ̀rí Olúwa yóò ti ṣe tọ̀ mí wá?”
[10] Dafidi kò sì fẹ́ mú àpótí ẹ̀rí Olúwa sọ́dọ̀ rẹ̀ sí ìlú Dafidi; ṣùgbọ́n Dafidi sì mú un yà sí ilé Obedi-Edomu ará Gitti.
[11] Àpótí ẹ̀rí Olúwa sì gbé ní ilé Obedi-Edomu ará Gitti ní oṣù mẹ́ta; Olúwa sì bùkún fún Obedi-Edomu, àti gbogbo ilé rẹ̀.
[12] A sì rò fún Dafidi ọba pé, “Olúwa ti bùkún fún ilé Obedi-Edomu, àti gbogbo èyí tí í ṣe tirẹ̀, nítorí àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run.” Dafidi sì lọ, ó sì mú àpótí ẹ̀rí náà gòkè láti ilé Obedi-Edomu wá sí ìlú Dafidi pẹ̀lú ayọ̀.
[13] Ó sì ṣe nígbà tí àwọn ènìyàn tí ó ru àpótí ẹ̀rí Olúwa bá sì ṣí ẹsẹ̀ mẹ́fà, òun a sì fi màlúù àti ẹran àbọ́pa rú ẹbọ.
[14] Dafidi sì fi gbogbo agbára rẹ̀ jó níwájú Olúwa; Dafidi sì wọ efodu ọ̀gbọ̀.
[15] Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi àti gbogbo ilé Israẹli sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa gòkè wá, pẹ̀lú ìhó ayọ̀, àti pẹ̀lú ìró ìpè.
[16] Bí àpótí ẹ̀rí Olúwa sì ti wọ ìlú Dafidi wá; Mikali ọmọbìnrin Saulu sì wo láti ojú fèrèsé, ó sì rí Dafidi ọba ń fò sókè ó sì ń jó níwájú Olúwa; òun sì kẹ́gàn rẹ̀ ní ọkàn rẹ̀.
[17] Wọ́n sì mú àpótí ẹ̀rí Olúwa náà wá, wọ́n sì gbé e kalẹ̀ sípò rẹ̀ láàrín àgọ́ náà tí Dafidi pa fún un. Dafidi sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ níwájú Olúwa.
[18] Dafidi sì parí ìṣe ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ náà, ó sì súre fún àwọn ènìyàn náà ní orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
[19] Ó sì pín fún gbogbo àwọn ènìyàn náà, àní fún gbogbo ọ̀pọ̀ ènìyàn Israẹli, àti ọkùnrin àti obìnrin; fún olúkúlùkù ìṣù àkàrà kan àti ekìrí ẹran kan, àti àkàrà díndín kan. Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì túká lọ, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀.
[20] Dafidi sì yípadà láti súre fún àwọn ará ilé rẹ̀, Mikali ọmọbìnrin Saulu sì jáde láti wá pàdé Dafidi, ó sì wí pé, “Báwo ni ọba Israẹli ṣe ṣe ara rẹ̀ lógo bẹ́ẹ̀ lónìí, tí ó bọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ lónìí lójú àwọn ìránṣẹ́bìnrin àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn lásán tí ń bọ́ra rẹ̀ sílẹ̀.”
[21] Dafidi sì wí fún Mikali pé, “Níwájú Olúwa ni, ẹni tí ó yàn mí fẹ́ ju baba rẹ lọ, àti ju gbogbo ìdílé rẹ lọ, láti fi èmi ṣe olórí àwọn ènìyàn Olúwa, àní lórí Israẹli, èmi ó sì súre níwájú Olúwa.
[22] Èmi ó sì tún rẹ ara mi sílẹ̀ jú bẹ́ẹ̀ lọ, èmi ó sì ṣe aláìníyìn lójú ara mi, àti lójú àwọn ìránṣẹ́bìnrin náà ti ìwọ wí, lọ́dọ̀ wọn náà ni èmi ó sì ní ògo.”
[23] Mikali ọmọbìnrin Saulu kò sì bí ọmọ, títí o fi di ọjọ́ ikú rẹ̀ nítorí tí ó sọ̀rọ̀-òdì yìí sí Dafidi.