Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 4:03

[1] Lẹ́yìn ikú Saulu, Dafidi ti ibi tí ó ti ṣẹ́gun àwọn ará Amaleki bọ̀, ó sì dúró ní Siklagi ní ọjọ́ méjì.

[2] Ní ọjọ́ kẹta, ọkùnrin kan dé láti ibi ibùdó Saulu, pẹ̀lú aṣọ rẹ̀ tí ó ti ya; àti erùpẹ̀ ní orí rẹ̀. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Dafidi, ó wólẹ̀ fún un láti bu ọlá fún un.

[3] Dafidi sì béèrè pé, “Ibo ni ìwọ ti wá?” “Èmi sá láti ibùdó àwọn ọmọ Israẹli.”

[4] Dafidi béèrè pé, “Kí ni ó ṣẹlẹ̀?” “Sọ fún mi.” Ó wí pé, “Àwọn ọkùnrin náà sá láti ojú ogun. Ọ̀pọ̀ wọn ṣubú, wọ́n sì kú. Saulu àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin Jonatani sì kú pẹ̀lú.”

[5] Nígbà náà, ní Dafidi sọ fún ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún un pé, “Báwo ni o ṣe mọ̀ pé Saulu àti ọmọkùnrin rẹ̀ Jonatani ti kú.”

[6] Ọ̀dọ́mọkùnrin náà sọ pé, “Mo wà ní orí òkè Gilboa níbẹ̀ ni Saulu fi ara tí ọkọ̀ rẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹlẹ́ṣin sì ń lépa rẹ̀.

[7] Nígbà tí ó wò yíká, tí ó rí mí, ó pè mi, mo sì wí pé, ‘Kí ni mo lè ṣe?’

[8] “Ó bi mí wí pé, ‘Ta ni ìwọ?’ “Mo dáhùn pé, ‘Ará a Amaleki.’

[9] “Nígbà náà ó wí fún mi pé, ‘Dúró lórí ì mi kí o sì pa mí! Èmi wà nínú ìrora ikú, ṣùgbọ́n mo wà láààyè.’

[10] “Nígbà náà, mo dúró lórí i rẹ̀, mo sì pa á nítorí mo mọ̀ wí pé, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ṣubú, kò le è yè mọ́. Mo sì mú adé tí ó wà lórí rẹ̀, idẹ tí ó wà ní apá a rẹ̀, mo sì kó wọn wá síbí fún olúwa mi.”

[11] Nígbà náà ni, Dafidi àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, di aṣọ wọn mú, wọ́n sì fà á ya.

[12] Wọ́n ṣọ̀fọ̀, wọ́n sì sọkún, wọ́n sì gbààwẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́ fún Saulu àti ọmọ rẹ̀ Jonatani àti fún àwọn ọmọ-ogun Olúwa, àti fún àwọn ilé Israẹli, nítorí wọ́n ti ṣubú nípa idà.

[13] Dafidi sọ fún ọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún un pé, “Níbo ni ó ti wá?” O dáhùn pé, “Ọmọ àlejò ni mo jẹ́, ará Amaleki.”

[14] Dafidi béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni ó dé tí ìwọ kò fi bẹ̀rù láti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè láti fi pa ẹni àmì òróró Olúwa?”

[15] Nígbà náà Dafidi pe ọ̀kan nínú ọkùnrin, ó sì wí pé, “Lọ, gbé e lulẹ̀!” Nígbà náà ó gbé e lulẹ̀, ó sì kú.

[16] Nítorí Dafidi wí fún un pé, “Ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò wà lórí ara rẹ, nítorí ẹnu ara rẹ ni o fi sọ pé, ‘Mo pa ẹni àmì òróró Olúwa.’ ”

[17] Dafidi sì fi orin ọ̀fọ̀ yìí ṣọ̀fọ̀ lórí Saulu àti lórí Jonatani ọmọ rẹ̀,

[18] Ó sì pàṣẹ pé kí a kọ́ àwọn ọkùnrin Juda ní orin arò yìí tí ó jẹ́ ti ọrun (a kọ ọ́ sí inú ìwé Jaṣari):

[19] “Ògo rẹ, Israẹli ni a pa ní òkè gíga rẹ. Wò bí àwọn alágbára ṣe ń ṣubú!

[20] “Ẹ má ṣe sọ ọ́ ní Gati, ẹ má ṣe kéde rẹ̀ ní òpópónà Aṣkeloni, kí àwọn ọmọbìnrin Filistini má bá à yọ̀, kí àwọn ọmọbìnrin aláìkọlà má ba à dunnú.

[21] “Ẹ̀yin òkè Gilboa, kí ẹ̀yin kí ó má ṣe rí ìrì tàbí òjò, tàbí oko tí ó mú èso ọrẹ wá. Nítorí ibẹ̀ ni asà alágbára ti ṣègbé, asà Saulu, bí ẹni pé a kò fi òróró yàn án.

[22] “Ọrun Jonatani kì í padà bẹ́ẹ̀ ni idà Saulu kì í padà lásán, láì kan ẹ̀jẹ̀ àwọn tí a pa, àti ẹran àwọn alágbára.

[23] Saulu àti Jonatani— ní ọjọ́ ayé, wọ́n fẹ́ràn ara, wọn sì dùn, ní ikú, wọn kò sì yà ara wọ́n. Wọ́n yára ju idì lọ, wọ́n lágbára ju kìnnìún lọ.

[24] “Ẹ̀yin ọmọbìnrin Israẹli, ẹ sọkún lórí Saulu, ẹni tí ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára wọ̀ yín, ẹni tí ó fi wúrà sí ara aṣọ yín.

[25] “Wò ó bí alágbára ti ṣubú ní ojú ogun! Jonatani, ìwọ tí a pa ní òkè gíga.

[26] Ọkàn mi gbọgbẹ́ fún ọ Jonatani arákùnrin mi; ìwọ ṣọ̀wọ́n fún mi. Ìfẹ́ rẹ sí mi jẹ́ ìyanu, ó jẹ́ ìyanu ju ti obìnrin lọ.

[27] “Wò ó bí alágbára ti ṣubú! Ohun ìjà sì ti ṣègbé!”

Ìwé Samuẹli Kejì — Chapters