[1] Wọ̀nyí sì ni ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dafidi. “Dafidi ọmọ Jese, àní ọkùnrin tí a ti gbéga, ẹni àmì òróró Ọlọ́run Jakọbu, àti olórin dídùn Israẹli wí pé,
[2] “Ẹ̀mí Olúwa sọ ọ̀rọ̀ nípa mi, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ń bẹ ní ahọ́n mi.
[3] Ọlọ́run Israẹli ni, àpáta Israẹli sọ fún mi pé, ‘Ẹnìkan ti ń ṣe alákòóso ènìyàn lódodo, tí ń ṣàkóso ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.
[4] Yóò sì dàbí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nígbà tí oòrùn bá là, òwúrọ̀ tí kò ní ìkùùkuu, nígbà tí koríko tútù bá hù wá láti ilẹ̀ lẹ́yìn òjò.’
[5] “Lóòtítọ́ ilé mi kò rí bẹ́ẹ̀ níwájú Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ó ti bá mi dá májẹ̀mú àìnípẹ̀kun, tí a túnṣe nínú ohun gbogbo, tí a sì pamọ́; nítorí pé gbogbo èyí ni ìgbàlà, àti gbogbo ìfẹ́ mi, ilé mi kò lè ṣe kí ó má dàgbà.
[6] Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ọmọ Beliali yóò dàbí ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n tí a ṣá tì, nítorí pé a kò lè fi ọwọ́ kó wọn.
[7] Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí yóò tọ́ wọn yóò fi irin àti ọ̀pá ọ̀kọ̀ ṣagbára yí ara rẹ̀ ká; wọ́n ó jóná lúúlúú níbìkan náà.”
[8] Wọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn akọni ọkùnrin tí Dafidi ní: Joṣebu-Basṣebeti ará Takemoniti ni olórí àwọn balógun, òun sì ni akọni rẹ̀ tí ó pa ẹgbẹ̀rin (800) ènìyàn lẹ́ẹ̀kan náà.
[9] Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni Eleasari ọmọ Dodo ará Ahohi, ọ̀kan nínú àwọn alágbára ọkùnrin mẹ́ta ti ó wà pẹ̀lú Dafidi, nígbà tí wọ́n pe àwọn Filistini ní ìjà, àwọn ọkùnrin Israẹli sì ti lọ kúrò.
[10] Òun sì dìde, ó sì kọlu àwọn Filistini títí ọwọ́ fi kún un, ọwọ́ rẹ̀ sì lẹ̀ mọ́ idà; Olúwa sì ṣiṣẹ́ ìgbàlà ńlá lọ́jọ́ náà, àwọn ènìyàn sì padà bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ láti kó ìkógun.
[11] Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni Ṣamma ọmọ Agee ará Harari, àwọn Filistini sì kó ara wọn jọ láti piyẹ́, oko kan sì wà níbẹ̀ tí ó kún fun lẹntili, àwọn ọmọ-ogun Israẹli sì sá kúrò níwájú àwọn Filistini.
[12] Ṣamma sì dúró láàrín méjì ilẹ̀ náà, ó sì gbà á sílẹ̀, ó sì pa àwọn Filistini Olúwa sì ṣe ìgbàlà ńlá.
[13] Mẹ́ta nínú àwọn ọgbọ̀n ìjòyè sọ̀kalẹ̀, wọ́n sì tọ Dafidi wá ní àkókò ìkórè nínú ihò Adullamu, ọ̀wọ́ àwọn Filistini sì dó sí àfonífojì Refaimu.
[14] Dafidi sì wà nínú odi, ibùdó àwọn Filistini sì wà ní Bẹtilẹhẹmu nígbà náà.
[15] Dafidi sì ń pòǹgbẹ, ó wí báyìí pé, “Ta ni yóò fún mi mu nínú omí kànga tí ń bẹ ní Bẹtilẹhẹmu, èyí tí ó wà ní ìhà ẹnu-bodè.”
[16] Àwọn ọkùnrin alágbára mẹ́ta sì la ogún àwọn Filistini lọ, wọ́n sì fa omi láti inú kànga Bẹtilẹhẹmu wá, èyí tí ó wà ní ìhà ẹnu-bodè, wọ́n sì mú tọ Dafidi wá, òun kò sì fẹ́ mu nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n ó tú u sílẹ̀ fún Olúwa.
[17] Òun sì wí pé, “Kí a má rí, Olúwa, tí èmi ó fi ṣe èyí; ṣé èyí ni ẹ̀jẹ̀ àwọn ọkùnrin tí ó lọ tí àwọn tí ẹ̀mí wọn lọ́wọ́?” Nítorí náà òun kò sì fẹ́ mú un. Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin alágbára mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ṣe.
[18] Abiṣai, arákùnrin Joabu, ọmọ Seruiah, òun náà ni pàtàkì nínú àwọn mẹ́ta. Òun ni ó sì gbé ọ̀kọ̀ rẹ̀ sókè sí ọ̀ọ́dúnrún (300) ènìyàn, ó sì pa wọ́n, ó sì ní orúkọ nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.
[19] Ọlọ́lá jùlọ ni òun jẹ́ nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ó sì jẹ́ olórí fún wọn, ṣùgbọ́n òun kò tó àwọn mẹ́ta ìṣáájú.
[20] Benaiah, ọmọ Jehoiada, ọmọ akọni ọkùnrin kan tí Kabṣeeli, ẹni tí ó pọ̀ ní iṣẹ́ agbára, òun pa àwọn ọmọ Arieli méjì ti Moabu; ó sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ó sì pa kìnnìún kan nínú ihò lákoko òjò-dídì.
[21] Ó sì pa ará Ejibiti kan, ọkùnrin tí ó dára láti wò, ará Ejibiti náà sì ní ọ̀kọ̀ kan ní ọwọ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n Benaiah sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ, pẹ̀lú ọ̀pá ní ọwọ́, ó sì gba ọ̀kọ̀ náà lọ́wọ́ ará Ejibiti náà, ó sì fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ pa á.
[22] Nǹkan wọ̀nyí ní Benaiah ọmọ Jehoiada ṣe, ó sì ní orúkọ nínú àwọn ọkùnrin alágbára mẹ́ta náà.
[23] Nínú àwọn ọgbọ̀n náà, òun ní ọlá jùlọ, ṣùgbọ́n òun kò tó àwọn mẹ́ta ti ìṣáájú. Dafidi sì fi í ṣe ìgbìmọ̀ rẹ̀.
[24] Ọ̀kan nínú àwọn ọgbọ̀n náà: Asaheli arákùnrin Joabu sì Jásí Elhanani ọmọ Dodo ti Bẹtilẹhẹmu;
[25] Ṣamma ará Haroditi, Elika ará Harodi.
[26] Helesi ará Palti, Ira ọmọ Ikẹsi ará Tekoa;
[27] Abieseri ará Anatoti, Sibekai ará Huṣati;
[28] Salmoni ará Ahohi, Maharai ará Netofa;
[29] Heledi ọmọ Baanah, ará Netofa, Ittai ọmọ Ribai to Gibeah ti àwọn ọmọ Benjamini;
[30] Benaiah ará Piratoni, Hiddai ti àfonífojì Gaaṣi,
[31] Abi-Alboni ará Arbati, Asmafeti Barhumiti;
[32] Eliaba ará Ṣaalboni, àwọn ọmọ Jaṣeni, Jonatani;
[33] ọmọ Ṣamma ará Harari, Ahiamu ọmọ Ṣarari ará Harari;
[34] Elifeleti ọmọ Ahasbai, ọmọ ará Maakati, Eliamu ọmọ Ahitofeli ará Giloni;
[35] Hesro ará Karmeli, Paarai ará Arba;
[36] Igali ọmọ Natani ti Soba, Bani ará Gadi;
[37] Seleki ará Ammoni, Naharai ará Beeroti, ẹni tí ń ru ìhámọ́ra Joabu ọmọ Seruiah;
[38] Ira ará Itri, Garebu ará Itri.
[39] Uriah ará Hiti. Gbogbo wọn jẹ́ mẹ́tàdínlógójì.