Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 3:58

[1] Ǹjẹ́ ní ti ìdáwó fún àwọn ènìyàn mímọ́, bí mo tí wí fún àwọn ìjọ Galatia, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní kí ẹ ṣe.

[2] Ní ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, kí olúkúlùkù yín fi sínú ìṣúra lọ́dọ̀ ara rẹ̀ ni apá kan, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe rere fún ún, ki ó má ṣe si ìkójọ nígbà tí mo bá dé.

[3] Àti nígbà ti mo bá dé, àwọn ẹni tí ẹ bá yàn, àwọn ni èmi ó rán láti mú ẹ̀bùn yín gòkè lọ si Jerusalẹmu.

[4] Bí ó bá sì yẹ kí èmí lọ pẹ̀lú, wọn ó sì bá mi lọ.

[5] Ṣùgbọ́n èmi yóò tọ̀ yin wá, nígbà tí èmí bá ti kọjá láàrín Makedonia: nítorí èmi yóò kọjá láàrín Makedonia.

[6] Bóyá èmi ó sì dúró pẹ̀lú yín, tàbí kí n tilẹ̀ lo àkókò òtútù, ki ẹ̀yin lé sìn mí ni ọ̀nà àjò mí, níbikíbi tí mo bá ń lọ.

[7] Nítorí èmi kò fẹ́ kan ri yín kí èmi sì ṣe bẹ́ẹ̀ kọjá lọ; nítorí èmi ń retí àti dúró lọ́dọ̀ yín díẹ̀, bí Olúwa bá fẹ́.

[8] Ṣùgbọ́n èmi yóò dúró ni Efesu títí dí Pentikosti.

[9] Nítorí pé ìlẹ̀kùn ńlá láti ṣe iṣẹ́ gidi ṣí sílẹ̀ fún mí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn ọ̀tá tí ń bẹ.

[10] Ǹjẹ́ bí Timotiu bá dé, ẹ jẹ́ kí ó wà lọ́dọ̀ yín láìbẹ̀rù, nítorí òun ń ṣé iṣẹ́ Olúwa, bí èmi pẹ̀lú ti ń ṣe.

[11] Nítorí náà kí ẹnikẹ́ni má ṣe kẹ́gàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ sín ín jáde lọ́nà àjò ni àlàáfíà, kí òun lè tọ̀ mí wá; nítorí tí èmí ń fi ojú sí ọ̀nà fún wíwá rẹ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin.

[12] Ṣùgbọ́n ní ti Apollo arákùnrin wa, mo bẹ̀ ẹ́ púpọ̀ láti tọ̀ yín wá pẹ̀lú àwọn arákùnrin, ṣùgbọ́n kì í ṣe ìfẹ́ rẹ̀ rárá láti wà nísinsin yìí, ṣùgbọ́n òun yóò wá nígbà tí ààyè bá ṣí sílẹ̀ fún un.

[13] Ẹ máa ṣọ́ra, ẹ dúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́, ẹ ṣe bi ọkùnrin tí ó ní ìgboyà, ẹ jẹ́ alágbára.

[14] Ẹ máa ṣe ohun gbogbo nínú ìfẹ́.

[15] Ǹjẹ́ mo bẹ̀ yín ará, ẹ ṣá mọ ilé Stefana pé, àwọn ni ẹni àkọ́kọ́ tó gba Jesu ní Akaia, àti pé, wọn sì tí fi ará wọn fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ènìyàn mímọ́.

[16] Kí ẹ̀yin tẹríba fún irú àwọn báwọ̀nyí, àti fún olúkúlùkù olùbáṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú wa tí ó sì ń ṣe làálàá.

[17] Mo láyọ̀ fún wíwá Stefana àti Fortunatu àti Akaiku, nítorí èyí tí ó kù nípá tí yín wọ́n ti fi kún un.

[18] Nítorí tí wọ́n tu ẹ̀mí mí lára àti tiyín: nítorí náà, ẹ máa gba irú àwọn ti ó rí bẹ́ẹ̀.

[19] Àwọn ìjọ ni Asia kí í yín. Akuila àti Priskilla kí í yín púpọ̀ nínú Olúwa, pẹ̀lú ìjọ tí ó wà ni ilé wọn.

[20] Gbogbo àwọn arákùnrin kí í yín. Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín.

[21] Ìkíni ti èmi Paulu, láti ọwọ́ èmi tìkára mi wá.

[22] Bí ẹnikẹ́ni kò bá ní ìfẹ́ Jesu Kristi Olúwa, jẹ́ kí ó dì ẹni ìfibú. Máa bọ Olúwa wa!

[23] Oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa kí ó wà pẹ̀lú yín!

[24] Ìfẹ́ mi wá pẹ̀lú gbogbo yín nínú Kristi Jesu. Àmín.

Ìwé sí àwọn ará Kọrinti Kìn-ín-ní — Chapters