Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 6:24

[1] Ẹ máa tẹ̀lé àpẹẹrẹ mi, gẹ́gẹ́ bí èmi náà ti ń tẹ̀lé àpẹẹrẹ Kristi.

[2] Èmí yìn yín fún rírántí mi nínú ohun gbogbo àti fún dídi gbogbo ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ ọ yín mú ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí mo ṣe fi lélẹ̀ fún un yín.

[3] Ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí ẹ̀yin mọ̀ pé, Kristi ni orí olúkúlùkù ọkùnrin, orí obìnrin sì ni ọkọ rẹ̀ àti orí Kristi sì ní Ọlọ́run.

[4] Gbogbo ọkùnrin tó bá borí rẹ̀ nígbà tó bá ń gbàdúrà tàbí sọtẹ́lẹ̀ kò bọ̀wọ̀ fún orí rẹ̀.

[5] Bẹ́ẹ̀ náà ni obìnrin tí ó bá ń gbàdúrà tàbí tí ó bá ń sọtẹ́lẹ̀ láìbo orí rẹ̀, kò bu ọlá fún orí ara rẹ̀ nítorí ọ̀kan náà ni pẹ̀lú ẹni tí ó fárí.

[6] Ṣùgbọ́n tí obìnrin bá kọ̀ láti bo orí rẹ̀, ẹ jẹ́ kí ó gé irun rẹ̀. Bí ó bá sì jẹ́ nǹkan ìtìjú fún un láti gé irun orí rẹ́, nígbà náà kí ó fi gèlè bo orí rẹ̀.

[7] Ṣùgbọ́n ọkùnrin kò ní láti fi nǹkan bo orí rẹ́ nígbà tí ó bá ń sìn, nítorí àwòrán àti ògo Ọlọ́run ni òun í ṣe, ṣùgbọ́n ògo ọkùnrin ni obìnrin í ṣe.

[8] Ọkùnrin kò ti inú obìnrin wá, ṣùgbọ́n a yọ obìnrin jáde lára ọkùnrin,

[9] bẹ́ẹ̀ ni a kò dá ọkùnrin fún àǹfààní obìnrin ṣùgbọ́n a da obìnrin fún ọkùnrin.

[10] Nítorí ìdí èyí àti nítorí àwọn angẹli, ni obìnrin ṣe gbọdọ̀ ní àmì àṣẹ rẹ̀ ní orí rẹ̀.

[11] Ẹ rántí pé, nínú ètò Ọlọ́run obìnrin kò lè wà láìsí ọkùnrin, bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin kò lè wà láàsí obìnrin.

[12] Lóòtítọ́ láti ara ọkùnrin ni a ti yọ obìnrin jáde bẹ́ẹ̀ sì ni ọkùnrin tipasẹ̀ obìnrin wa. Ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ohun gbogbo ti wà.

[13] Kí ni ẹ̀yìn fúnra yín rò lórí ọ̀rọ̀ yìí? Ǹjẹ́ ó tọ̀nà fún obìnrin láti máa gbàdúrà Ọlọ́run ní gbangba láìbo orí rẹ̀ bí?

[14] Ǹjẹ́ ìwà abínibí yín kò ha kọ́ yín pé, bí ọkùnrin bá ní irun gígùn, àbùkù ni ó jẹ́ fún un.

[15] Ṣùgbọ́n bí obìnrin bá ní irun gígùn, ògo ni ó jẹ́ fún un nítorí irun gígùn tí a fi fún un jẹ́ ìbòrí fún un.

[16] Ṣùgbọ́n tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yìí, ohun kan tí mo lè sọ sí gbogbo rẹ̀ ni pé, a kò ní ìlànà tí ó yàtọ̀ sí èyí tí mo ti sọ, pé obìnrin gbọdọ̀ fi gèlè bo orí rẹ̀ nígbà tí ó bá ń sọtẹ́lẹ̀ tàbí tí ó bá ń gbàdúrà láàrín ìjọ Ọlọ́run.

[17] Nínú àwọn àlàkalẹ̀ èmi ko ni yìn yín nítorí pé bí ẹ bá péjọ kì í ṣe fún rere bí ko ṣe fún búburú.

[18] Lọ́nà kìn-ín-ní, mo gbọ́ pe ìyapa máa ń wà láàrín yín ní ìgbà tí ẹ bá péjọpọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìjọ, mo sì gba èyí gbọ́ dé ààyè ibìkan.

[19] Kò sí àní àní, ìyàtọ̀ gbọdọ̀ wa láàrín yín, kí àwọn tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run láàrín yín le farahàn kedere.

[20] Nígbà tí ẹ bá pàdé láti jẹun, kì í ṣe oúnjẹ alẹ́ Olúwa ni ẹ máa ń jẹ.

[21] Ṣùgbọ́n tí ara yín, nígbà tí ẹ bá fẹ́ jẹun, olúkúlùkù yín a máa sáré jẹ oúnjẹ rẹ̀ láìdúró de ẹnìkejì rẹ̀. Ebi a sì máa pa wọ́n, ẹlòmíràn wọ́n sì ń mu àmuyó àti àmupara.

[22] Ṣé ẹ̀yin kò ní ilé tí ẹ ti lè jẹ, tí ẹ sì ti lè mu ni? Tàbí ẹ̀yin ń gan ìjọ Ọlọ́run ni? Ẹ̀yin sì ń dójútì àwọn aláìní? Kín ni kí èmi ó wí fún un yín? Èmi yóò ha yìn yín nítorí èyí? A! Rárá o. Èmi kọ́, n kò ní yìn yín.

[23] Nítorí èyí tí èmi gbà lọ́wọ́ Olúwa ni mo ti fi fún un yin. Ní alẹ́ ọjọ́ tí Judasi fihàn, Olúwa Jesu Kristi mú àkàrà.

[24] Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún àkàrà náà tan, ó bù ú, ó fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ gbà kí ẹ sì jẹ, èyí ní ara mi tí a fi fún un yín. Ẹ máa ṣe eléyìí ni rántí mi.”

[25] Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lẹ́yìn oúnjẹ alẹ́, ó sì mú ago wáìnì, ó sì wí pé, “Ago yìí ni májẹ̀mú tuntun nínú ẹ̀jẹ̀ mi, ẹ máa ṣe èyí, nígbàkígbà ti ẹ̀yìn bá ń mu ú, ní ìrántí mi.”

[26] Nítorí nígbàkígbà tí ẹ bá ń jẹ lára àkàrà yìí, tí ẹ sì ǹ mu nínú ago yìí, ni ẹ tún sọ nípa ikú Olúwa. Ẹ máa ṣe eléyìí títí yóò fi padà dé.

[27] Nítorí náà tí ẹnikẹ́ni bá jẹ lára àkàrà yìí, tí ẹ sì ń mu nínú ago Olúwa yìí, ní ọ̀nà tí kò bójúmu, yóò jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ sí ara àti ẹ̀jẹ̀ Olúwa.

[28] Ìdí nìyìí tí ó fi yẹ kí ènìyàn yẹ ara rẹ̀ wò dáradára kí ó tó jẹ lára àkàrà nà án àti kí ó tó mu nínú ago náà.

[29] Nítorí tí ẹ bá jẹ lára àkàrà, tí ẹ sì mu nínú ago láìyẹ, tí ẹ kò ronú ara Kristi àti nǹkan tí ó túmọ̀ sí, ẹ̀ ń jẹ, ẹ sì ń mú ẹ̀bi ìdájọ́ Ọlọ́run wá sórí ara yín.

[30] Ìdí nìyìí tí ọ̀pọ̀ yín fi di ẹni tí kò lágbára mọ́, tí ọ̀pọ̀ yín sì ń ṣàìsàn, àwọn mìíràn nínú yín tilẹ̀ ti sùn.

[31] Ṣùgbọ́n tí ẹ bá yẹ ara yín wò dáradára, kí ẹ tó jẹ ẹ́, a kì yóò dá yín lẹ́jọ́.

[32] Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá dá wa lẹ́jọ́, láti ọwọ́ Olúwa ni a ti nà wá, kí a má ba à dá wa lẹ́bi pẹ̀lú ayé.

[33] Nítorí náà, ẹ̀yin arákùnrin mi ọ̀wọ́n, nígbàkígbà ti ẹ bá péjọ láti jẹ́ oúnjẹ alẹ́ Olúwa, tàbí fún ìsìn oúnjẹ alẹ́ Olúwa, ẹ dúró de ara yín.

[34] Bí ebi bá ń pa ẹnikẹ́ni nínú yin, kí ó jẹun láti ilé wá, kí ó má ba á mú ìjìyà wá sórí ara rẹ̀ nígbà tí ẹ bá péjọ. Tí mo bá dé, èmi yóò máa sọ̀rọ̀ lórí àwọn kókó-ọ̀rọ̀ ìyókù tí n kò ì ti fẹnu bà lẹ́sẹẹsẹ.

Ìwé sí àwọn ará Kọrinti Kìn-ín-ní — Chapters