Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 5:17

[1] Paulu, ẹni ti a pé láti jẹ́ aposteli Kristi Jesu nípa ìfẹ́ Ọlọ́run àti Sostene arákùnrin wa,

[2] Sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run ni Kọrinti, sí àwọn ti a sọ di mímọ́ nínú Kristi Jesu àti àwọn ti a pè láti jẹ́ mímọ́ pẹ̀lú gbogbo ènìyàn ni ibikíbi ti ń pe orúkọ Olúwa wa Jesu Kristi ẹni ti ń ṣe Olúwa tiwọn àti ti àwa náà:

[3] Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Olúwa wa tí í ṣe Jesu Kristi.

[4] Nígbà gbogbo ni mo ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tó fi fún un yín nínú Kristi Jesu.

[5] Nítorí nínú rẹ̀ ni a ti sọ yín di ọlọ́rọ̀ nínú ọ̀rọ̀ sísọ yín gbogbo àti nínú ìmọ̀ yín gbogbo.

[6] Nítorí ẹ̀rí wa nínú Kristi ni a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nínú yín.

[7] Nítorí náà ẹ̀yin kò ṣe aláìní nínú èyíkéyìí ẹ̀bùn ẹ̀mí, bí ẹ̀yin ṣe ń retí ìfarahàn Olúwa wa Jesu Kristi.

[8] Òun yóò sì mú yín dúró títí dé òpin, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ́ aláìlábùkù ní ọjọ́ Olúwa wa Jesu Kristi.

[9] Ọlọ́run, nípasẹ̀ ẹni ti a pè yín sínú ìdàpọ̀ pẹ̀lú Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi Olúwa wa, jẹ́ Olóòtítọ́.

[10] Mo bẹ̀ yín ẹ̀yin ara, ní orúkọ Olúwa wa Jesu Kristi, pé kí gbogbo yín fohùn ṣọ̀kan kí ó máa ṣe sí ìyapa láàrín yín, àti pé kí a lè ṣe yín pé ní inú àti ìmọ̀ kan náà.

[11] Ẹ̀yin ará mi, àwọn kan láti ilé Kloe sọ di mí mọ̀ fún mi pé ìjà ń bẹ́ láàrín yín.

[12] Ohun tí mo ń sọ ní pé, olúkúlùkù yín ń wí pé, “Èmí tẹ̀lé Paulu”; “Èmi tẹ̀lé Apollo”; òmíràn wí pé, “Èmi tẹ̀lé Kefa, Peteru”; àti ẹlòmíràn wí pé, “Èmi tẹ̀lé Kristi.”

[13] Ǹjẹ́ a ha pín Kristi bí? Ṣé a kan Paulu mọ́ àgbélébùú fún un yín bí? Ǹjẹ́ a tẹ̀ yín bọ omi ní orúkọ Paulu bí?

[14] Inú mi dún púpọ̀ pé èmi kò tẹ ẹnikẹ́ni nínú yín bọ omi yàtọ̀ sí Krisipu àti Gaiusi.

[15] Nítorí náà kò sí ẹni tí ó lè sọ pé òun ṣe ìtẹ̀bọmi ní orúkọ èmi fúnra ara mi.

[16] (Bẹ́ẹ̀ ni, mo tún tẹ ìdílé Stefana bọ omi; lẹ́yìn èyí, èmí kò rántí pé mo tẹ ẹnikẹ́ni bọ omi mọ́ níbikíbi).

[17] Nítorí Kristi kò rán mi láti máa ṣe ìtẹ̀bọmi, ṣùgbọ́n ó rán mi láti máa wàásù ìyìnrere: kì í ṣe nípa ọgbọ́n ènìyàn, kí a máa ṣe sọ àgbélébùú Kristi dí aláìlágbára.

[18] Nítorí pé òmùgọ̀ ni ọ̀rọ̀ àgbélébùú jẹ́ sí àwọn tí ń ṣègbé, ṣùgbọ́n fún àwa tí a ń gbàlà ó jẹ́ agbára Ọlọ́run.

[19] Nítorí a tí kọ ọ́ pé: “Èmi yóò pa ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n run, òye àwọn olóye ni Èmi yóò sọ di asán.”

[20] Àwọn ọlọ́gbọ́n náà ha dá? Àwọn akọ̀wé náà ha dà? Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ayé yìí ha dà? Ọlọ́run kò ha ti sọ ọgbọ́n ayé yìí di aṣiwèrè?

[21] Nítorí pé, nínú ọgbọ́n Ọlọ́run, ayé kò le mọ̀ òun nípa ọgbọ́n àti ìṣeféfé wọn. Ó sì gba gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́ là nípa ìwàásù tí àwọn aráyé pè ní òmùgọ̀ àti ọ̀rọ̀ ọ yẹ̀yẹ́.

[22] Nítorí pé àwọn Júù ń béèrè àmì, àwọn Helleni sí ń ṣàfẹ́rí ọgbọ́n,

[23] ṣùgbọ́n àwa ń wàásù Kristi ti a kàn mọ́ àgbélébùú, òkúta ìkọ̀sẹ̀ àwọn Júù àti òmùgọ̀ fún àwọn kèfèrí.

[24] Ṣùgbọ́n sí àwọn tí Ọlọ́run tí pè, àti àwọn Júù àti àwọn Giriki, Kristi ni agbára Ọlọ́run, àti ọgbọ́n Ọlọ́run.

[25] Nítorí pé òmùgọ̀ Ọlọ́run jù ọgbọ́n ènìyàn lọ; àti aláìlera Ọlọ́run ni agbára jù ìlera ènìyàn lọ.

[26] Ará, ẹ kíyèsi ohun tí ẹ jẹ́ nígbà tí a pè yín. Kì í ṣe ọ̀pọ̀ yín jẹ ọlọ́gbọ́n nípa àgbékalẹ̀ ti ènìyàn, tàbí ọ̀pọ̀ nínú yín jẹ́ ènìyàn pàtàkì, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ọ̀pọ̀ nínú yín jẹ́ ọlọ́lá nípa ibi tí a gbé bí i.

[27] Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tí yàn àwọn òmùgọ̀ ayé láti fi dààmú àwọn ọlọ́gbọ́n; Ọlọ́run sì ti yàn àwọn ohun aláìlera ayé láti fi dààmú àwọn ohun tí ó ni agbára.

[28] Àti àwọn ohun tí ayé tí kò ní ìyìn, àti àwọn ohun tí a kẹ́gàn, ni Ọlọ́run sì ti yàn, àní àwọn ohun tí kò sí, láti sọ àwọn ohun tí ó wà di asán.

[29] Nítorí kí ó má ba à sí ẹnìkan tí yóò ṣògo níwájú rẹ̀.

[30] Nítorí rẹ̀ ni ẹ̀yin ṣe wà nínú Kristi Jesu ẹni ti ó jásí ọgbọ́n fún wa láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run—èyí ń ni, òdodo, ìwà mímọ́ àti ìràpadà wa.

[31] Nítorí náà, bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹni ti ó bá ń ṣògo kí ó máa ṣògo nínú Olúwa.”

Ìwé sí àwọn ará Kọrinti Kìn-ín-ní — Chapters