Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 4:24

[1] Báwo ni wúrà ṣe sọ ògo dídán rẹ̀ nù, wúrà dídára di àìdán! Òkúta ibi mímọ́ wá túká sí oríta gbogbo òpópó.

[2] Báwo ni àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Sioni tí ó ṣe iyebíye, tí wọ́n fi wúrà dídára ṣe wá dàbí ìkòkò amọ̀ lásán iṣẹ́ ọwọ́ amọ̀kòkò!

[3] Àwọn ajáko pèsè ọmú wọn fún ìtọ́jú àwọn ọmọ wọn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi wá láì lọ́kàn bí ògòǹgò ní aginjù.

[4] Nítorí òǹgbẹ, ahọ́n àwọn ọmọ ọwọ́ lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu wọn; àwọn ọmọdé bẹ̀bẹ̀ fún oúnjẹ, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó fi fún wọn.

[5] Àwọn tí ó ń jẹ ohun dáradára di òtòṣì ní òpópó. Àwọn tí a fi aṣọ dáradára wọ̀ ni wọ́n sùn ní orí òkìtì eérú.

[6] Ìjìyà àwọn ènìyàn mi tóbi ju ti Sodomu lọ, tí a sí ní ipò ní òjijì láìsí ọwọ́ láti ràn án lọ́wọ́.

[7] Ọmọ ọba ọkùnrin wọn mọ́ ju òjò-dídì, wọ́n sì funfun ju wàrà lọ wọ́n ni ìtọ́jú bí iyùn pupa, ìrísí wọn dàbí safire.

[8] Ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n dúdú ju èédú; wọn kò sì dá wọn mọ̀ ní òpópó. Ara wọn hun mọ́ egungun; ó sì gbẹ bí igi gbígbẹ.

[9] Àwọn tí ó kù nípasẹ̀ idà sàn ju àwọn tí ìyàn pa; tí ó wọ àkísà ebi, tí ó ń ṣòfò fún àìní oúnjẹ láti inú pápá.

[10] Pẹ̀lú ọwọ́ àwọn obìnrin aláàánú ni wọ́n ṣe ọmọ wọn jẹ tí ó di oúnjẹ fún wọn nígbà tí a pa àwọn ènìyàn mi run.

[11] Olúwa ti fi ihò kíkún fún ìbínú rẹ̀; ó sì tú ìbínú gbígbóná rẹ̀ jáde. Ó da iná ní Sioni tí ó jó ìpìlẹ̀ rẹ̀ run.

[12] Àwọn ọba ayé kò gbàgbọ́, tàbí àwọn ènìyàn ayé, wí pé àwọn ọ̀tá àti aninilára le wọ odi ìlú Jerusalẹmu.

[13] Èyí ṣẹlẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn wòlíì àti àìṣedéédéé àwọn olórí àlùfáà, tí ó ta ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodo sílẹ̀ láàrín rẹ̀.

[14] Nísinsin yìí wọ́n ń rìn kiri ní òpópó bí ọkùnrin tí ó fọ́jú. Ẹ̀jẹ̀ ara wọn sọ wọ́n di àbàwọ́n tí kò sẹ́ni tó láyà láti fọwọ́ kan aṣọ wọn.

[15] “Lọ kúrò! Ẹ̀yin di aláìmọ́!” ni àwọn ènìyàn ń kígbe sí wọn. “Ẹ lọ! Ẹ lọ! Ẹ má ṣe fọwọ́ kàn wá!” Àwọn ènìyàn láàrín orílẹ̀-èdè wí pé, “Wọn kì yóò tẹ̀dó síbí mọ́.”

[16] Olúwa ti tú wọn ká fúnra rẹ̀; kò sí bojútó wọn mọ́. Kò sí ọ̀wọ̀ fún olórí àlùfáà mọ́, àti àánú fún àwọn àgbàgbà.

[17] Síwájú sí i, ojú wa kùnà fún wíwo ìrànlọ́wọ́ asán; láti orí ìṣọ́ wa ni à ń wò fún orílẹ̀-èdè tí kò le gbà wá là.

[18] Wọ́n ń ṣọ́ wa kiri, àwa kò sì le rìn ní òpópó wa mọ́. Òpin wa ti súnmọ́, ọjọ́ wa sì níye nítorí òpin wa ti dé.

[19] Àwọn tí ń lé wa yára ju idì ojú ọ̀run lọ; wọ́n lé wa ní gbogbo orí òkè wọ́n sì gẹ̀gùn dè wá ní aginjù.

[20] Ẹni àmì òróró Olúwa, èémí ìyè wa, ni wọ́n fi tàkúté wọn mú. Àwa rò pé lábẹ́ òjìji rẹ̀ ni àwa yóò máa gbé láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo.

[21] Ẹ yọ̀ kí inú yín sì dùn, ẹ̀yin ọmọbìnrin Edomu, ẹ̀yin tó ń gbé ní ilẹ̀ Usi. Ṣùgbọ́n, a ó gbé ago náà kọjá sọ́dọ̀ rẹ pẹ̀lú; ìwọ yóò yó bí ọ̀mùtí, ìwọ yóò sì rìn ní ìhòhò.

[22] Ìwọ ọmọbìnrin Sioni, ìjìyà rẹ yóò dópin; kò ní mú ìgbèkùn rẹ pẹ́ mọ́. Ṣùgbọ́n, ìwọ ọmọbìnrin Edomu, yóò jẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ní yà yóò sì fi àìṣedéédéé rẹ hàn kedere.

Ìwé Ẹkún Jeremiah — Chapters