[1] Èmi ni ọkùnrin tí ó rí ìpọ́njú pẹ̀lú ọ̀pá ìbínú rẹ.
[2] Ó ti lé mi jáde ó sì mú mi rìn nínú òkùnkùn ju ti ìmọ́lẹ̀.
[3] Nítòótọ́, ó ti yí ọwọ́ rẹ̀ padà sí mi síwájú àti síwájú sí i ní gbogbo ọjọ́.
[4] Ó jẹ́ kí àwọ̀ mi àti ẹran-ara mi gbó ó sì tún ṣẹ́ egungun mi.
[5] Ó ti fi mí sí ìgbèkùn, ó sì ti yí mi ká pẹ̀lú ìkorò àti làálàá.
[6] Ó mú mi gbé nínú òkùnkùn, bí ti àwọn tó ti kú fún ìgbà pípẹ́.
[7] Ó ti tì mí mọ́ ilé, nítorí náà n kò le è sálọ; ó ti fi ẹ̀wọ̀n mú mi mọ́lẹ̀.
[8] Pàápàá nígbà tí mo ké fún ìrànlọ́wọ́, ó kọ àdúrà mi.
[9] Ó fi ògiri òkúta dí ọ̀nà mi; ó sì mú ọ̀nà mi wọ́.
[10] Bí i beari tí ó dùbúlẹ̀, bí i kìnnìún tí ó sá pamọ́.
[11] Ó wọ́ mi kúrò ní ọ̀nà, ó tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ ó fi mi sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́.
[12] Ó fa ọfà rẹ̀ yọ ó sì fi mí ṣe ohun ìtafàsí.
[13] Ó fa ọkàn mí ya pẹ̀lú ọfà nínú àkọ̀ rẹ̀.
[14] Mo di ẹni yẹ̀yẹ́ láàrín àwọn ènìyàn mi; wọn yẹ̀yẹ́ mi pẹ̀lú orin ní gbogbo ọjọ́.
[15] Ó ti kún mi pẹ̀lú ewé kíkorò àti ìdààmú bí omi.
[16] Ó ti fi òkúta kán eyín mi; ó ti tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ nínú eruku.
[17] Mo ti jìnnà sí àlàáfíà; mo ti gbàgbé ohun tí àṣeyege ń ṣe.
[18] Nítorí náà mo wí pé, “Ògo mi ti lọ àti ìrètí mi nínú Olúwa.”
[19] Mo ṣe ìrántí ìpọ́njú àti ìdààmú mi, ìkorò àti ìbànújẹ́.
[20] Mo ṣèrántí wọn, ọkàn mi sì gbọgbẹ́ nínú mi.
[21] Síbẹ̀, èyí ni mo ní ní ọkàn àti nítorí náà ní mo nírètí.
[22] Nítorí ìfẹ́ Olúwa tí ó lágbára ni àwa kò fi ṣègbé, nítorí ti àánú rẹ kì í kùnà.
[23] Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àárọ̀; títóbi ni òdodo rẹ̀.
[24] Mo wí fún ara mi, ìpín mi ni Olúwa; nítorí náà èmi yóò dúró dè ọ́.
[25] Dídára ni Olúwa fún àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ̀, sí àwọn tí ó ń wá a.
[26] Ó dára kí a ní sùúrù fún ìgbàlà Olúwa.
[27] Ó dára fún ènìyàn láti gbé àjàgà nígbà tí ó wà ní èwe.
[28] Jẹ́ kí ó jókòó ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, nítorí Olúwa ti fi fún un.
[29] Jẹ́ kí ó bo ojú rẹ̀ sínú eruku— ìrètí sì lè wà.
[30] Jẹ́ kí ó fi ẹ̀rẹ̀kẹ́ fún àwọn tí yóò gbá a, sì jẹ́ kí ó wà ní ìdójútì.
[31] Ènìyàn kò di ìtanù lọ́dọ̀ Olúwa títí láé.
[32] Lóòtítọ́ ó mú ìbànújẹ́ wá, yóò fi àánú hàn, nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ̀.
[33] Nítorí kò mọ̀ ọ́n mọ̀ mú ìpọ́njú wá tàbí ìrora wá fún ọmọ ènìyàn.
[34] Láti tẹ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n ní ilẹ̀ náà.
[35] Láti ṣẹ́ ọmọ ènìyàn fún ẹ̀tọ́ rẹ̀ níwájú Ọ̀gá-ògo jùlọ,
[36] láti yí ìdájọ́ ènìyàn padà, ǹjẹ́ Olúwa kò rí ohun bẹ́ẹ̀.
[37] Ta ni yóò sọ̀rọ̀ tí yóò rí bẹ́ẹ̀ tí Olúwa kò bá fi àṣẹ sí i.
[38] Ǹjẹ́ kì í ṣe láti ẹnu Ọ̀gá-ògo jùlọ ni rere àti búburú tí ń wá?
[39] Kí ló dé tí ẹ̀dá alààyè ṣe ń kùn nígbà tí ó bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀?
[40] Ẹ jẹ́ kí a yẹ ọ̀nà wa, kí a sì dán an wò, kí a sì tọ Olúwa lọ.
[41] Ẹ jẹ́ kí a gbé ọkàn àti ọwọ́ wa sókè sí Ọlọ́run ní ọ̀run, kí a wí pé,
[42] “Àwa ti ṣẹ̀ a sì ti ṣọ̀tẹ̀ ìwọ kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá.
[43] “Ìwọ fi ìbínú bo ara rẹ ìwọ sì ń lépa wa; ìwọ ń parun láìsí àánú.
[44] Ìwọ ti fi àwọsánmọ̀ bo ara rẹ pé kí àdúrà wa má ba à dé ọ̀dọ̀ rẹ.
[45] Ó ti sọ wá di èérí àti ààtàn láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo.
[46] “Gbogbo àwọn ọ̀tá wa ti la ẹnu wọn gbòòrò sí wa.
[47] Àwa ti jìyà àti ìparun, nínú ìbẹ̀rù àti ewu.”
[48] Omijé ń sàn ní ojú mi bí odò nítorí a pa àwọn ènìyàn mi run.
[49] Ojú mi kò dá fún omijé, láì sinmi,
[50] títí ìgbà tí Olúwa yóò síjú wolẹ̀ láti òkè ọ̀run tí yóò sì rí i.
[51] Ohun tí mo rí mú ìbẹ̀rù wá ọkàn mi nítorí gbogbo àwọn obìnrin ìlú mi.
[52] Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí dẹ mí bí ẹyẹ.
[53] Wọ́n gbìyànjú láti mú òpin dé bá ayé mi nínú ihò wọ́n sì ju òkúta lù mí.
[54] Orí mi kún fún omi, mo sì rò pé ìgbẹ̀yìn dé.
[55] Mo pe orúkọ rẹ, Olúwa, láti ọ̀gbun ìsàlẹ̀ ihò.
[56] Ìwọ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi, “Má ṣe di etí rẹ sí igbe ẹ̀bẹ̀ mi fún ìtura.”
[57] O wá tòsí nígbà tí mo ké pè ọ́, o sì wí pé, “Má ṣe bẹ̀rù.”
[58] Olúwa, ìwọ gba ẹjọ́ mi rò, o ra ẹ̀mí mi padà.
[59] O ti rí i, Olúwa, búburú tí a ṣe sí mi. Gba ẹjọ́ mi ró!
[60] Ìwọ ti rí ọ̀gbun ẹ̀san wọn, gbogbo ìmọ̀ wọn sí mi.
[61] Olúwa ìwọ ti gbọ́ ẹ̀gàn wọn àti ìmọ̀ búburú wọn sí mi,
[62] ohun tí àwọn ọ̀tá mi ń sọ sí mi ní gbogbo ọjọ́.
[63] Wò wọ́n! Ní jíjòkòó tàbí ní dídìde, wọ́n ń ṣẹlẹ́yà mi nínú orin wọn.
[64] Olúwa san wọ́n lẹ́san ohun tí ó tọ́ sí wọn fún ohun tí ọwọ́ wọn ti ṣe.
[65] Fi ìbòjú bò wọ́n ní ọkàn, kí o sì fi wọ́n ré.
[66] Ni wọ́n lára kí o sì pa wọ́n run pẹ̀lú ìbínú, lábẹ́ ọ̀run Olúwa.