Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 6:52

[1] Ìpín fún ẹ̀yà Juda, ní agbo ilé agbo ilé, títí dé agbègbè Edomu, títí dé aginjù Sini ní òpin ìhà gúúsù.

[2] Ààlà wọn ní ìhà gúúsù bẹ̀rẹ̀ láti etí òpin ìhà gúúsù Òkun Iyọ̀,

[3] ó sì gba gúúsù Akrabbimu lọ, títí dé Sini àti sí iwájú ìhà gúúsù Kadeṣi-Barnea. Nígbà náà ó sì tún kọjá Hesroni lọ sí Adari, ó sì tún yípo yíká lọ sí Karka.

[4] Ó tún kọjá lọ sí Asmoni, ó sì papọ̀ mọ́ Wadi ti Ejibiti, ó parí sí Òkun. Èyí ni ààlà wọn ní ìhà gúúsù.

[5] Ààlà wọn ní ìhà ìlà-oòrùn ní Òkun Iyọ̀ títí dé ẹnu Jordani. Ààlà àríwá bẹ̀rẹ̀ láti etí òkun ní ẹnu Jordani,

[6] ààlà náà sì tún dé Beti-Hogla, ó sì lọ sí ìhà àríwá Beti-Araba. Ààlà náà sì tún dé ibi Òkúta Bohani ti ọmọ Reubeni.

[7] Ààlà náà gòkè lọ títí dé Debiri láti àfonífojì Akori, ó sì yípadà sí àríwá Gilgali, èyí tí ń bẹ ní iwájú òkè Adummimu, tí ń bẹ ní ìhà gúúsù odò náà. Ó sì tẹ̀síwájú sí apá omi En-Ṣemeṣi, ó sì jáde sí En-Rogeli.

[8] Ààlà náà sì tún gòkè lọ sí àfonífojì Beni-Hinnomu ní ìhà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ gúúsù ti Jebusi (tí í ṣe Jerusalẹmu). Ó sì gòkè lọ sí orí òkè tí ó wà lórí àfonífojì Hinnomu tí ń bẹ ní ìpẹ̀kun àfonífojì Refaimu ní ìhà àríwá.

[9] Ààlà náà sì lọ láti orí òkè lọ sí ìsun omi Nefitoa, ó sì jáde sí ìlú òkè Efroni, ó sì lọ sí apá ìsàlẹ̀ Baalahi (tí í ṣe, Kiriati-Jearimu).

[10] Ààlà tí ó yípo láti Baalahi lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn sí òkè Seiri, ó sì lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àríwá òkè Jearimu (tí í ṣe, Kesaloni), ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Beti-Ṣemeṣi, ó sì kọjá lọ sí Timna.

[11] Ààlà náà sì lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àríwá òkè Ekroni, ó sì yípadà lọ sí Ṣikkeroni, ó sì yípadà lọ sí òkè Baalahi, ó sì dé Jabneeli, ààlà náà sì parí sí Òkun.

[12] Ààlà ìwọ̀-oòrùn sì jẹ́ agbègbè Òkun Ńlá. Ìwọ̀nyí ni ààlà àyíká ènìyàn Juda ní agbo ilé wọn.

[13] Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Olúwa pa fún Joṣua, ó fi ìpín fún Kalebu ọmọ Jefunne, ìpín ní Juda—Kiriati-Arba, tí í ṣe Hebroni. (Arba sì ní baba ńlá Anaki.)

[14] Kalebu sì lé àwọn ọmọ Anaki mẹ́ta jáde láti Hebroni; Ṣeṣai, Ahimani, àti Talmai, ìran Anaki.

[15] Ó sì wọ́de ogun láti ibẹ̀ lọ bá àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Debiri (tí à ń pè ní Kiriati-Seferi nígbà kan rí).

[16] Kalebu sì wí pé, “Èmi yóò fi ọmọbìnrin mi Aksa fún ọkùnrin tí ó bá kọlu Kiriati-Seferi, tí ó sì gbà á ní ìgbéyàwó.”

[17] Otnieli ọmọ Kenasi, arákùnrin Kalebu, sì gbà á, báyìí ni Kalebu sì fi ọmọbìnrin rẹ̀ Aksa fún un ní ìyàwó.

[18] Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Aksa lọ sí ọ̀dọ̀ Otnieli, ó rọ̀ ọ́ kí ó béèrè ilẹ̀ oko lọ́wọ́ baba rẹ̀. Nígbà náà ni Aksa sọ̀kalẹ̀ ní orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, Kalebu sì béèrè pé, “Kí ni kí èmi ṣe fún ọ?”

[19] Ó sì dáhùn pé, “Mo ń fẹ́ kí o ṣe ojúrere kan fún mi, nígbà ti o ti fún mi ní ilẹ̀ ní gúúsù, fún mi ní ìsun omi náà pẹ̀lú.” Kalebu sì fún un ní ìsun òkè àti ìsun ìsàlẹ̀.

[20] Èyí ni ilẹ̀ ìní ẹ̀yà àwọn ọmọ Juda gẹ́gẹ́ bi ìdílé wọn.

[21] Ìlú ìpẹ̀kun gúúsù ti ẹ̀yà Juda ní gúúsù ní ààlà Edomu nìwọ̀nyí: Kabṣeeli, Ederi, Jaguri,

[22] Kina, Dimona, Adada,

[23] Kedeṣi, Hasori, Itina,

[24] Sifi, Telemu, Bealoti,

[25] Hasori Hadatta, Kerioti Hesroni (tí í ṣe Hasori),

[26] Amamu, Ṣema, Molada,

[27] Hasari Gada, Heṣmoni, Beti-Peleti,

[28] Hasari-Ṣuali, Beerṣeba, Bisiotia,

[29] Baalahi, Limu, Esemu,

[30] Eltoladi, Kesili, Horma,

[31] Siklagi, Madmana, Sansanna,

[32] Leboati, Ṣilhimu, Aini àti Rimoni, àpapọ̀ ìlú mọ́kàndínlọ́gbọ̀n àti àwọn ìletò wọn.

[33] Ní ìhà ìwọ̀-oòrùn ẹsẹ̀ òkè: Eṣtaoli, Sora, Aṣna,

[34] Sanoa, Eni-Gannimu, Tapua, Enamu,

[35] Jarmatu, Adullamu, Soko, Aseka,

[36] Ṣaaraimu, Adittaimu àti Gedera (tàbí Gederotaimu). Ìlú mẹ́rìnlá àti àwọn ìletò wọn.

[37] Senani, Hadaṣa, Migdali Gadi,

[38] Dileani, Mispa, Jokteeli,

[39] Lakiṣi, Boskati, Egloni,

[40] Kabboni, Lamasi, Kitlisi,

[41] Gederoti, Beti-Dagoni, Naama àti Makkeda, ìlú mẹ́rìndínlógún àti ìletò wọn.

[42] Libina, Eteri, Aṣani,

[43] Hifita, Aṣna, Nesibu,

[44] Keila, Aksibu àti Meraṣa: ìlú mẹ́sàn-án àti àwọn ìletò wọn.

[45] Ekroni, pẹ̀lú ibùgbé àti àwọn ìletò rẹ̀ tó yí i ká,

[46] ìwọ̀-oòrùn Ekroni, gbogbo èyí tí ń bẹ nítòsí Aṣdodu, pẹ̀lú àwọn ìletò wọn,

[47] Aṣdodu, agbègbè ìlú rẹ̀ àti ìletò; àti Gasa, ìlú rẹ̀ àti ìletò, títí ó fi dé odò Ejibiti àti agbègbè Òkun Ńlá.

[48] Ní ilẹ̀ òkè náà: Ṣamiri, Jattiri, Soko,

[49] Dannah, Kiriati-Sannnah (tí í ṣe Debiri),

[50] Anabu, Eṣitemo, Animu,

[51] Goṣeni, Holoni àti Giloni, ìlú mọ́kànlá àti ìletò wọn.

[52] Arabu, Duma, Eṣani,

[53] Janimu, Beti-Tapua, Afeka,

[54] Hamuta, Kiriati-Arba (tí í ṣe, Hebroni) àti Ṣiori: ìlú mẹ́sàn-án àti àwọn ìletò rẹ̀

[55] Maoni, Karmeli, Sifi, Jutta,

[56] Jesreeli, Jokdeamu, Sanoa,

[57] Kaini, Gibeah àti Timna: ìlú mẹ́wàá àti àwọn ìletò wọn.

[58] Halhuli, Beti-Suri, Gedori,

[59] Maarati, Beti-Anoti àti Eltekoni: ìlú mẹ́fà àti àwọn ìletò wọn.

[60] Kiriati-Baali (tí í ṣe, Kiriati-Jearimu) àti Rabba ìlú méjì àti ìletò wọn.

[61] Ní aginjù: Beti-Araba, Middini, Sekaka,

[62] Nibṣani, Ìlú Iyọ̀ àti En-Gedi: ìlú mẹ́fà àti ìletò wọn.

[63] Juda kò lè lé àwọn ọmọ Jebusi jáde, tí wọ́n ń gbé ní Jerusalẹmu. Àwọn ará Jebusi sì ń gbé pẹ̀lú àwọn ènìyàn Juda títí dí òní.

Ìwé Joṣua — Chapters