Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 3:02

[1] Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí àwọn ará Israẹli ṣẹ́gun, tí wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn ní ìlà-oòrùn Jordani, láti odò Arnoni dé òkè Hermoni, pẹ̀lú gbogbo ìhà ìlà-oòrùn aginjù:

[2] Sihoni ọba àwọn Amori, tí ó jẹ ọba ní Heṣboni. Ó ṣe àkóso láti Aroeri tí ń bẹ ní etí odò Arnoni, láti ìlú tó wà ní àárín àfonífojì náà dé odò Jabbok, èyí tí ó jẹ́ ààlà àwọn ọmọ Ammoni. Pẹ̀lú ìdajì àwọn ará Gileadi.

[3] Ó sì ṣe àkóso ní orí ìlà-oòrùn aginjù láti Òkun Kinnereti sí ìhà Òkun ti aginjù (ti o túmọ̀ sí Òkun Iyọ̀), sí Beti-Jeṣimoti, àti láti gúúsù lọ dé ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ òkè Pisga.

[4] Àti agbègbè Ogu ọba Baṣani, ọ̀kan nínú àwọn tí ó kù nínú àwọn ará Refaimu, ẹni tí ó jẹ ọba ní Aṣtarotu àti Edrei.

[5] Ó ṣe àkóso ní orí òkè Hermoni, Saleka, Baṣani títí dé ààlà àwọn ènìyàn Geṣuri àti Maakati, àti ìdajì Gileadi dé ààlà Sihoni ọba Heṣboni.

[6] Mose ìránṣẹ́ Olúwa àti àwọn ọmọ Israẹli sì borí wọn. Mose ìránṣẹ́ Olúwa sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹ̀yà Reubeni, àwọn ẹ̀yà Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase kí ó jẹ́ ohun ìní wọn.

[7] Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí Joṣua àti àwọn ọmọ Israẹli ṣẹ́gun ní ìhà ìwọ̀-oòrùn Jordani, láti Baali-Gadi ní àfonífojì Lebanoni sí òkè Halaki, èyí tí o lọ sí ọ̀nà Seiri (Joṣua sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹ̀yà Israẹli ní ilẹ̀ ìní gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà wọn:

[8] ilẹ̀ òkè, ní ẹsẹ̀ òkè ní ìhà ìwọ̀-oòrùn òkè aginjù, ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè, ní aginjù àti nì gúúsù ilẹ̀ àwọn ará: Hiti, Amori, Kenaani, Peresi, Hifi àti àwọn ará Jebusi).

[9] Ọba Jeriko, ọ̀kan ọba Ai (tí ó wà nítòsí Beteli), ọ̀kan

[10] ọba Jerusalẹmu, ọ̀kan ọba Hebroni, ọ̀kan

[11] ọba Jarmatu, ọ̀kan ọba Lakiṣi, ọ̀kan

[12] ọba Egloni, ọ̀kan ọba Geseri, ọ̀kan

[13] ọba Debiri, ọ̀kan ọba Gederi, ọ̀kan

[14] ọba Horma, ọ̀kan ọba Aradi, ọ̀kan

[15] ọba Libina, ọ̀kan ọba Adullamu, ọ̀kan

[16] ọba Makkeda, ọ̀kan ọba Beteli, ọ̀kan

[17] ọba Tapua, ọ̀kan ọba Heferi, ọ̀kan

[18] ọba Afeki, ọ̀kan ọba Laṣaroni, ọ̀kan

[19] ọba Madoni, ọ̀kan ọba Hasori, ọ̀kan

[20] ọba Ṣimroni-Meroni, ọ̀kan ọba Akṣafu, ọ̀kan

[21] ọba Taanaki, ọ̀kan ọba Megido, ọ̀kan

[22] ọba Kedeṣi, ọ̀kan ọba Jokneamu ni Karmeli, ọ̀kan

[23] ọba Dori (ní Nafoti Dori), ọ̀kan ọba Goyimu ní Gilgali, ọ̀kan

[24] ọba Tirsa, ọ̀kan. Gbogbo àwọn ọba náà jẹ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n.

Ìwé Joṣua — Chapters