[1] Èyí ni ìbùkún tí Mose ènìyàn Ọlọ́run bùkún fún àwọn ọmọ Israẹli kí ó tó kú.
[2] Ó sì wí pé, “Olúwa ti Sinai wá, ó sì yọ sí wọn láti Seiri wá ó sì tàn án jáde láti òkè Parani wá. Ó ti ọ̀dọ̀ ẹgbẹgbàarùn-ún àwọn mímọ́ wá láti ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni òfin kan a mú bí iná ti jáde fún wọn wá.
[3] Nítòótọ́, ó fẹ́ràn àwọn ènìyàn an rẹ̀, gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ wà ní ọwọ́ rẹ̀. Ní ẹsẹ̀ rẹ̀ ni wọ́n ti foríbalẹ̀, àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni wọ́n ti ń gba ọ̀rọ̀,
[4] òfin tí Mose fi fún wa, ìní ti ìjọ ènìyàn Jakọbu.
[5] Òun ni ọba lórí Jeṣuruni ní ìgbà tí olórí àwọn ènìyàn péjọpọ̀, pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà Israẹli.
[6] “Jẹ́ kí Reubeni yè kí ó má ṣe kú, tàbí kí ènìyàn rẹ mọ níwọ̀n.”
[7] Èyí ni ohun tí ó sọ nípa Juda: “Olúwa gbọ́ ohùn Juda kí o sì mú tọ àwọn ènìyàn rẹ̀ wá. Kí ọwọ́ rẹ̀ kí ó tó fún un, kí ó sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀!”
[8] Ní ti Lefi ó wí pé, “Jẹ́ kí Tumimu àti Urimu rẹ kí ó wà pẹ̀lú ẹni mímọ́ rẹ. Ẹni tí ó dánwò ní Massa, ìwọ bá jà ní omi Meriba.
[9] Ó wí fún baba àti ìyá rẹ pé, ‘Èmi kò buyì fún wọn.’ Kò mọ àwọn arákùnrin rẹ̀, tàbí mọ àwọn ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sì pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́.
[10] Ó kọ́ Jakọbu ní ìdájọ́ rẹ̀ àti Israẹli ní òfin rẹ̀. Ó mú tùràrí wá síwájú rẹ̀ àti ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ẹbọ sísun sórí i pẹpẹ rẹ̀.
[11] Bùsi ohun ìní rẹ̀, Olúwa, kí o sì tẹ́wọ́gbà iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Lu ẹgbẹ́ àwọn tí ó dìde sí i; àwọn tí ó kórìíra rẹ̀, kí wọn kí ó má ṣe dìde mọ́.”
[12] Ní ti Benjamini ó wí pé, “Jẹ́ kí olùfẹ́ Olúwa máa gbé ní àlàáfíà lọ́dọ̀ rẹ̀, òun a máa bò ó ní gbogbo ọjọ́, ẹni tí Olúwa fẹ́ràn yóò máa sinmi láàrín èjìká rẹ̀.”
[13] Ní ti Josẹfu ó wí pé, “Kí Olúwa bùkún ilẹ̀ rẹ, fún ohun iyebíye láti ọ̀run pẹ̀lú ìrì àti ibú tí ó ń bẹ níṣàlẹ̀;
[14] àti fún èso iyebíye tí ọ̀run mú wá àti ti ohun iyebíye tí ń dàgbà ní oṣooṣù;
[15] pẹ̀lú ohun pàtàkì òkè ńlá ìgbàanì àti fún ohun iyebíye ìgbà ayérayé;
[16] Pẹ̀lú ohun iyebíye ayé àti ẹ̀kún un rẹ̀ àti fún ìfẹ́ ẹni tí ó ń gbé inú igbó. Jẹ́ kí gbogbo èyí sinmi lé orí Josẹfu, lórí àtàrí ẹni tí ó yàtọ̀ láàrín àwọn arákùnrin rẹ̀.
[17] Ní ọláńlá ó dàbí àkọ́bí akọ màlúù; ìwo rẹ̀, ìwo àgbáǹréré ni. Pẹ̀lú wọn ni yóò fi ti àwọn orílẹ̀-èdè, pàápàá títí dé òpin ayé. Àwọn sì ni ẹgbẹẹgbàárùn mẹ́wàá Efraimu, àwọn sì ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún Manase.”
[18] Ní ti Sebuluni ó wí pé, “Yọ̀ Sebuluni, ní ti ìjáde lọ rẹ, àti ìwọ Isakari, nínú àgọ́ rẹ.
[19] Wọn yóò pe àwọn ènìyàn sórí òkè àti níbẹ̀ wọn yóò rú ẹbọ òdodo, wọn yóò mu nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ Òkun, nínú ìṣúra tí ó pamọ́ nínú iyanrìn.”
[20] Ní ti Gadi ó wí pé, “Ìbùkún ni ẹni tí ó mú Gadi gbilẹ̀! Gadi ń gbé níbẹ̀ bí kìnnìún, ó sì fa apá ya, àní àtàrí.
[21] Ó sì yan ilẹ̀ tí ó dára jù fún ara rẹ̀; ìpín olórí ni a sì fi fún un. Nígbà tí ó rí tí gbogbo àwọn ènìyàn péjọ, ó mú òdodo Olúwa ṣẹ, àti ìdájọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ Israẹli.”
[22] Ní ti Dani ó wí pé, “Ọmọ kìnnìún ni Dani, tí ń fò láti Baṣani wá.”
[23] Ní ti Naftali ó wí pé, “Ìwọ Naftali, kún fún ojúrere Ọlọ́run àti ìbùkún Olúwa; yóò jogún ìhà ìwọ̀-oòrùn àti gúúsù.”
[24] Ní ti Aṣeri ó wí pé, “Ìbùkún ọmọ ni ti Aṣeri; jẹ́ kí ó rí ojúrere láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀ kí ó sì ri ẹsẹ̀ rẹ̀ sínú òróró.
[25] Bàtà rẹ̀ yóò jẹ́ irin àti idẹ, agbára rẹ̀ yóò sì rí bí ọjọ́ rẹ̀.
[26] “Kò sí ẹlòmíràn bí Ọlọ́run Jeṣuruni, ẹni tí ń gun ọ̀run fún ìrànlọ́wọ́ rẹ àti ní ojú ọ̀run nínú ọláńlá rẹ̀.
[27] Ọlọ́run ayérayé ni ibi ìsádi rẹ, àti ní ìsàlẹ̀ ni apá ayérayé wà. Yóò lé àwọn ọ̀tá rẹ níwájú rẹ, ó sì wí pé, ‘Ẹ máa parun!’
[28] Israẹli nìkan yóò jókòó ní àlàáfíà, orísun Jakọbu nìkan ní ilẹ̀ ọkà àti ti ọtí wáìnì, níbi tí ọ̀run ti ń sẹ ìrì sílẹ̀.
[29] Ìbùkún ni fún ọ, Israẹli, ta ni ó dàbí rẹ, ẹni tí a gbàlà láti ọ̀dọ̀ Olúwa? Òun ni asà àti ìrànwọ́ rẹ̀ àti idà ọláńlá rẹ̀. Àwọn ọ̀tá rẹ yóò tẹríba fún ọ, ìwọ yóò sì tẹ ibi gíga wọn mọ́lẹ̀.”