[1] Mose àti àwọn àgbàgbà Israẹli pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé, “Pa gbogbo àṣẹ tí mo fún ọ lónìí mọ́.
[2] Nígbà tí o bá ti kọjá a Jordani sí inú ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ, gbé kalẹ̀ lára àwọn òkúta ńlá àti aṣọ ìlekè rẹ pẹ̀lú ẹfun.
[3] Kí ìwọ kí ó kọ gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí sára wọn nígbà tí ìwọ bá ti ń rékọjá láti wọ ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín ti ṣèlérí fún ọ.
[4] Àti nígbà tí o bá ti kọjá a Jordani, kí o gbé òkúta yìí kalẹ̀ sórí i Ebali, bí mo ti pa à láṣẹ fún ọ lónìí, kí o sì wọ̀ wọ́n pẹ̀lú ẹfun.
[5] Kọ́ pẹpẹ síbẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, pẹpẹ òkúta. Má ṣe lo ohun èlò irin lórí wọn.
[6] Kí ìwọ kí ó mọ pẹpẹ pẹ̀lú òkúta àìgbẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí ìwọ kí ó sì máa rú ẹbọ sísun ni orí rẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ.
[7] Rú ẹbọ àlàáfíà níbẹ̀ kí o jẹ wọ́n, kí o sì yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ.
[8] Kí o sì kọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ òfin yìí ketekete sórí òkúta tí ó ti gbé kalẹ̀.”
[9] Nígbà náà ni Mose àti àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi, sọ fún Israẹli pé, “Ẹ dákẹ́ ẹ̀yin Israẹli, kí ẹ sì fetísílẹ̀! O ti wá di ènìyàn Olúwa Ọlọ́run rẹ báyìí.
[10] Gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì tẹ̀lé àṣẹ àti òfin rẹ̀ tí mo ń fi fún ọ lónìí.”
[11] Ní ọjọ́ kan náà Mose pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé.
[12] Nígbà tí ìwọ bá ti kọjá a Jordani, àwọn ẹ̀yà yìí yóò dúró lórí òkè Gerisimu láti súre fún àwọn ènìyàn: Simeoni, Lefi, Juda, Isakari, Josẹfu àti Benjamini.
[13] Àwọn ẹ̀yà yìí yóò dúró lórí òkè Ebali láti gé ègún: Reubeni, Gadi, àti Aṣeri, àti Sebuluni, Dani, àti Naftali.
[14] Àwọn ẹ̀yà Lefi yóò ké sí gbogbo ènìyàn Israẹli ní ohùn òkè:
[15] “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó fín ère tàbí gbẹ́ òrìṣà ohun tí ó jẹ́ ìríra níwájú Olúwa, iṣẹ́ ọwọ́ oníṣọ̀nà tí ó gbé kalẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
[16] “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dójútì baba tàbí ìyá rẹ̀.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
[17] “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó yí òkúta ààlà aládùúgbò o rẹ̀.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
[18] “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣi afọ́jú lọ́nà ní ojú ọ̀nà.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
[19] “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó yí ìdájọ́ po fún àlejò, aláìní baba tàbí opó.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
[20] “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ìyàwó baba rẹ̀, nítorí ó ti dójúti ibùsùn baba rẹ̀.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
[21] “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹranko.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
[22] “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú arábìnrin rẹ̀, ọmọbìnrin baba rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin ìyá rẹ̀.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
[23] “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ìyá ìyàwó o rẹ̀.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
[24] “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó pa aládùúgbò rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
[25] “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti pa ènìyàn láìjẹ̀bi.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
[26] “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí kò gbé ọ̀rọ̀ òfin yìí ró nípa ṣíṣe wọ́n.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”