[1] Paulu tẹjúmọ́ ìgbìmọ̀, ó sì wí pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi tí ń fi gbogbo ẹ̀rí ọkàn rere lo ayé mi níwájú Ọlọ́run títí fi di òní yìí.”
[2] Nígbà yìí ni Anania olórí àlùfáà pàṣẹ fún àwọn tí ó dúró tí Paulu pé, kí wọn ó gbá a lẹ́nu.
[3] Nígbà náà ni Paulu wí fún un pé, “Ọlọ́run yóò lù ọ́, ìwọ ògiri tí a kùn lẹ́fun: ìwọ jókòó láti dá mi lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin, ṣùgbọ́n ìwọ gan an rú òfin nípa pípàṣẹ pé kí a lù mí!”
[4] Àwọn tí ó dúró tì Paulu sì wí pé, “Ìwọ́ ń gan olórí àlùfáà Ọlọ́run?”
[5] Paulu sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi kò mọ̀ pé olórí àlùfáà ni: nítorí a tí kọ ọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ olórí àwọn ènìyàn rẹ̀ ní búburú.’ ”
[6] Ṣùgbọ́n nígbà tí Paulu ṣàkíyèsí pé, apá kan wọn jẹ́ Sadusi, apá kan sì jẹ́ Farisi, ó kígbe ní ìgbìmọ̀ pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi jẹ́ Farisi, ọmọ Farisi sì ni èmi. Mo dúró ní ìdájọ́ nítorí ìrètí mi nínú àjíǹde òkú.”
[7] Nígbà tí ó sì tí wí èyí, ìyapa dé láàrín àwọn Farisi àti àwọn Sadusi: àjọ sì pín sì méjì.
[8] Nítorí tí àwọn Sadusi wí pé, kò sì àjíǹde, tàbí angẹli, tàbí ẹ̀mí: ṣùgbọ́n àwọn Farisi jẹ́wọ́ méjèèjì.
[9] Ó sì di ariwo ńlá, nínú àwọn olùkọ́ òfin tí ó wà ni apá tí àwọn Farisi dìde, wọ́n ń jà, wí pé, “Àwa kò rí ohun búburú kan lára ọkùnrin yìí,” wọ́n wí “àwa kò sì mọ̀ nítòótọ́ bí angẹli kan tàbí ẹ̀mí kan ń ba à sọ̀rọ̀?”
[10] Nígbà tí ìyapa sì di ńlá, tí olórí ogun bẹ̀rù kí Paulu má ba à di fífàya lọ́wọ́ wọn, ó pàṣẹ pé ki àwọn ọmọ-ogun sọ̀kalẹ̀ lọ láti fi ipá mú un kúrò láàrín wọn, kí wọn sì mú un wá sínú àgọ́ àwọn ológun.
[11] Ní òru ọjọ́ náà Olúwa dúró tì Paulu, ó wí pé, “Mú ọkàn le! Bí ìwọ ti jẹ́rìí fún mi ní Jerusalẹmu, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò lè ṣàìjẹ́rìí ni Romu pẹ̀lú.”
[12] Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn Júù kan dìtẹ̀, wọ́n fi ara wọn bú pé, àwọn kì yóò jẹ, bẹ́ẹ̀ ní àwọn kì yóò mú títí àwọn ó fi pa Paulu.
[13] Àwọn tí ó dìtẹ̀ yìí sì ju ogójì ènìyàn lọ.
[14] Wọ́n sì tọ olórí àwọn àlùfáà àti àwọn alàgbà lọ, wọn sì wí pé, “Àwa tí fi ara wa sínú ìdè ìbúra pé, a kì yóò tọ́ oúnjẹ kan wò títí àwa ó fi pa Paulu.
[15] Ǹjẹ́ nísinsin yìí kí ẹ̀yin pẹ̀lú àjọ ìgbìmọ̀ wí fún olórí ogun, kí ó mú un sọ̀kalẹ̀ tọ̀ yín wá, bí ẹni pé ẹ̀yin ń fẹ́ wádìí ọ̀ràn rẹ̀ dájúdájú. Kí ó tó súnmọ́ tòsí, àwa ó ti múra láti pa á.”
[16] Nígbà tí ọmọ arábìnrin Paulu sí gbúròó ìdìtẹ̀ wọn, ó lọ, ó sì wọ inú àgọ́ àwọn ológun lọ, ó sì sọ fún Paulu.
[17] Paulu sì pé ọ̀kan nínú àwọn balógun ọ̀run sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “Mú ọmọkùnrin yìí tọ olórí ogun lọ, nítorí ó ní nǹkan láti sọ fún un.”
[18] Ó mú un, ó sì sìn ín lọ sọ́dọ̀ olórí ogun. Balógun ọ̀rún náà wí pé, “Paulu òǹdè pè mi sọ́dọ̀ rẹ̀, ó síbẹ̀ mí pé ki èmi mú ọmọkùnrin yìí tọ̀ ọ́ wá, ẹni tí ó ní nǹkan láti sọ fún ọ.”
[19] Alábojútó-ogun fà á lọ́wọ́, ó sì lọ si apá kan, ó sì bi í léèrè níkọ̀kọ̀ pé, “Kín ni ohun tí ìwọ ní sọ fún mi?”
[20] Ó sì wí pé, “Àwọn Júù fi ìmọ̀ ṣọ̀kan láti wá bẹ̀ ọ́, kí o mú Paulu sọ̀kalẹ̀ wá sí àjọ ìgbìmọ̀ ní ọ̀la, bí ẹni pé àwọn ń fẹ́ béèrè nǹkan dájúdájú nípa rẹ̀.
[21] Nítorí náà má ṣe gbọ́ tiwọn, nítorí àwọn tí ó dènà dè é nínú wọn ju ogójì ọkùnrin lọ, tí wọ́n fi ara wọn bú pé, àwọn kì yóò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn kì yóò mu títí àwọn o fi pa á. Wọ́n sì ti múra tan nísinsin yìí, wọ́n ń retí ìdáhùn lọ́dọ̀ rẹ.”
[22] Nígbà náà ni olórí ogun fi ọmọ náà sílẹ̀ láti lọ, ó sí kìlọ̀ fún un pé, “Má ṣe wí fún ẹnìkan pé, ìwọ fi nǹkan wọ̀nyí hàn mi.”
[23] Ó sì pe méjì nínú àwọn balógun ọ̀run sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ múra igba ọmọ-ogun sílẹ̀, láti lọ sí Kesarea, àti àádọ́rin ẹlẹ́ṣin, àti igba ọlọ́kọ̀, ní wákàtí kẹta òru.
[24] Ó sì wí pé, kí wọn pèsè ẹṣin, kí wọ́n gbé Paulu gùn ún; kí wọ́n sì lè mú un dé ọ̀dọ̀ Feliksi baálẹ̀ ní àlàáfíà.”
[25] Ó sì kọ ìwé kan báyìí pé,
[26] Kilaudiu Lisia, sí Feliksi baálẹ̀ ọlọ́lá jùlọ, àlàáfíà.
[27] Àwọn Júù mú ọkùnrin yìí, wọ́n sì ń pète láti pa á, nígbà náà ni mo dé pẹ̀lú ogun, mo sì gbà á lọ́wọ́ wọn nígbà tí mo gbọ́ pé ará Romu ni í ṣe.
[28] Nígbà tí mo sì ń fẹ́ mọ ìdí ọ̀ràn tí wọn fi ẹ̀sùn kàn án sí, mo mú un sọ̀kalẹ̀ lọ sí àjọ ìgbìmọ̀ wọn.
[29] Ẹni tí mo rí pé, wọ́n fi sùn nítorí ọ̀ràn òfin wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò dá ọ̀ràn ohun kan tí ó tọ́ sí ikú àti sí ẹ̀wọ̀n.
[30] Nígbà tí a sì tí jí i sọ fún mi pé, wọn yóò dènà de ọkùnrin náà, mo rán an sí ọ lọ́gán, mo sì pàṣẹ fún àwọn olùfisùn rẹ̀ pẹ̀lú, láti sọ ohun tí wọ́n bá rí wí sí i níwájú rẹ̀.
[31] Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun gbe Paulu, wọ́n sì mú un lóru lọ si Antipatrisi, gẹ́gẹ́ bí a tí pàṣẹ fún wọn.
[32] Ní ọjọ́ kejì wọ́n sì fi àwọn ẹlẹ́ṣin sílẹ̀ láti máa bá a lọ, àwọn sì padà wá sínú àgọ́ àwọn ológun.
[33] Nígbà tí wọ́n dé Kesarea, tí wọ́n sí fi ìwé fún baálẹ̀, wọ́n mú Paulu pẹ̀lú wá síwájú rẹ̀.
[34] Nígbà tí ó sì ti ka ìwé náà, ó béèrè pé agbègbè ìlú wo ni tirẹ̀. Nígbà tí ó sì gbọ́ pé ará Kilikia ni;
[35] Ó wí pé, “Èmi yóò gbọ́ ẹjọ́ rẹ, nígbà tí àwọn olùfisùn rẹ pẹ̀lú bá dé.” Ó sì pàṣẹ pé kí wọn pa Paulu mọ́ ní abẹ́ àbojútó àwọn olùṣọ́ ní gbọ̀ngàn ìdájọ́ ààfin Herodu.