[1] Nínú ìwé mi ìṣáájú, Teofilu, ni mo ti kọ ní ti ohun gbogbo tí Jesu bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àti kọ́
[2] títí ó fi di ọjọ́ tí a gbà á lọ sókè ọ̀run, lẹ́yìn tí ó ti ti ipa Ẹ̀mí Mímọ́ pàṣẹ fún àwọn aposteli tí ó yàn.
[3] Lẹ́yìn ìjìyà rẹ̀, ó fi ara rẹ̀ hàn fún wọn àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí tí ó dájú pé òun wà láààyè. Ó fi ara hàn wọ́n fún ogójì ọjọ́, ó sì sọ̀rọ̀ nípa ìjọba Ọlọ́run.
[4] Ní àkókò kan bí ó sì ti ń jẹun pẹ̀lú wọn, ó pàṣẹ yìí fún wọn, “Ẹ má ṣe kúrò ní Jerusalẹmu, ṣùgbọ́n ẹ dúró de ìlérí tí Baba mi ṣe ìlérí, èyí tí ẹ̀yin tí gbọ́ lẹ́nu mi.
[5] Nítorí Johanu fi omi bamitiisi yín, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ díẹ̀ sí i, a o fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitiisi yín.”
[6] Nítorí náà, nígbà tí wọ́n sì péjọpọ̀, wọn bi í léèrè pé, “Olúwa, láti ìgbà yí lọ ìwọ yóò ha mú ìjọba padà fún Israẹli bí?”
[7] Ó sì wí fún wọn pé, “Kì í ṣe tiyín ni láti mọ àkókò tàbí ìgbà tí Baba ti yàn nípa àṣẹ òun tìkára rẹ̀.
[8] Ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò gba agbára, nígbà tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé e yín; ẹ̀yin yóò sì máa ṣe ẹlẹ́rìí mi ni Jerusalẹmu, àti ní gbogbo Judea, àti ní Samaria, àti títí dé òpin ilẹ̀ ayé.”
[9] Nígbà tí ó sì tí wí nǹkan wọ̀nyí, a gbà á sókè lójú wọn; ìkùùkuu àwọsánmọ̀ sì gbà á kúrò lójú wọn.
[10] Bí wọ́n sì ti tẹjúmọ́ ojú ọ̀run bí ó ti ń lọ sókè, lójijì, àwọn ọkùnrin méjì tí ó wọ aṣọ funfun dúró létí ọ̀dọ̀ wọn.
[11] Wọ́n sì wí pé, “Ẹ̀yin ara Galili, èéṣe tí ẹ̀yin fi dúró tí ẹ̀ ń wo ojú ọ̀run? Jesu yìí, tí a gbà sókè ọ̀run kúrò lọ́wọ́ yín, yóò padà bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ ti rí tí ó ń lọ sì ọ̀run.”
[12] Lẹ́yìn náà ni wọ́n padà sí Jerusalẹmu láti orí òkè ti a ń pè ni olifi, tí ó tó ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ ìsinmi kan.
[13] Nígbà tí wọn sì wọlé, wọn lọ sí iyàrá òkè, níbi tí wọ́n ń gbé. Àwọn tó wà níbẹ̀ ni: Peteru, Jakọbu, Johanu àti Anderu; Filipi àti Tomasi; Bartolomeu àti Matiu; Jakọbu ọmọ Alfeu, Simoni Sealoti, àti Judasi arákùnrin Jakọbu.
[14] Gbogbo àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn obìnrin àti Maria ìyá Jesu àti àwọn arákùnrin rẹ̀ fi ọkàn kan dúró láti máa gbàdúrà.
[15] Ní ọjọ́ wọ̀nyí ni Peteru sí dìde dúró láàrín àwọn ọmọ-ẹ̀yìn (iye àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ́ ọgọ́fà)
[16] ó wí pé, “Ẹ̀yin ará, ìwé mímọ́ kò lè ṣe kí ó má ṣẹ, èyí tí Ẹ̀mí Mímọ́ ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu Dafidi nípa Judasi, tí ó ṣe atọ́nà fún àwọn tí ó mú Jesu.
[17] Nítorí ọ̀kan nínú wa ni òun ń ṣe tẹ́lẹ̀, òun sì ní ìpín nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí.”
[18] (Judasi fi èrè àìṣòótọ́ rẹ̀ ra ilẹ̀ kan; nígbà tí ó sì ṣubú ni ògèdèǹgbé, ó bẹ́ ní agbede-méjì, gbogbo ìfun rẹ̀ sì tú jáde.
[19] Ó si di mí mọ̀ fún gbogbo àwọn ti ń gbé Jerusalẹmu; nítorí náà ni wọ́n fi ń pè ilẹ̀ náà ni Alkedama ní èdè wọn, èyí sì ni, Ilẹ̀ Ẹ̀jẹ̀.)
[20] Peteru sì wí pé, “Nítorí a ti kọ ọ́ nípa rẹ̀ nínú Ìwé Saamu pé, “ ‘Jẹ́ ki ibùgbé rẹ̀ di ahoro, kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé inú rẹ̀,’ àti, “ ‘Ipò rẹ̀ ni kí ẹlòmíràn kí ó gbà.’
[21] Nítorí náà, ó di dandan láti yan ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ti ń bá wa rìn ni gbogbo àkókò tí Jesu Olúwa ń wọlé, tí ó sì jáde láàrín wa.
[22] Bẹ́ẹ̀ láti ìgbà bamitiisi Johanu títí ó fi di ọjọ́ náà ti a gbe é lọ sókè kúrò lọ́dọ̀ wa. Ó yẹ kí ọ̀kan nínú àwọn wọ̀nyí ṣe ẹlẹ́rìí àjíǹde rẹ̀ pẹ̀lú wa.”
[23] Wọn sì yan àwọn méjì, Josẹfu tí a ń pè ní Barsaba (ẹni tí a sọ àpèlé rẹ̀ ni Justu) àti Mattia.
[24] Wọn sì gbàdúrà, wọn sì wí pé, “Olúwa, ìwọ mọ ọkàn gbogbo ènìyàn, fihàn wá nínú àwọn méjì yìí, èwo ni ìwọ yàn
[25] kí ó lè gba ipò nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ aposteli yìí, èyí tí Judasi kúrò nínú rẹ̀, ki òun kí ó lè lọ sí ipò ti ara rẹ̀.”
[26] Wọ́n sì dìbò fún wọn; ìbò sí mú Mattia; a sì kà á mọ́ àwọn aposteli mọ́kànlá.