Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 4:35

[1] Ǹjẹ́ àǹfààní wo ní Júù ní? Tàbí kín ni èrè ilà kíkọ?

[2] Púpọ̀ lọ́nà gbogbo; pàtàkì jùlọ ni pé àwọn ni a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lé lọ́wọ́.

[3] Ǹjẹ́ kí ha ni bí àwọn kan jẹ́ aláìgbàgbọ́? Àìgbàgbọ́ wọn yóò ha sọ òtítọ́ Ọlọ́run di asán bí?

[4] Kí a má rí! Kí Ọlọ́run jẹ́ olóòtítọ́, àti olúkúlùkù ènìyàn jẹ́ èké; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Kí a lè dá ọ láre nínú ọ̀rọ̀ rẹ, ṣùgbọ́n kí ìwọ lè borí nígbà tí ìwọ bá wá sí ìdájọ́.”

[5] Ṣùgbọ́n bí àìṣòdodo wa bá fi òdodo Ọlọ́run hàn, kín ni àwa ó wí? Ọlọ́run ha jẹ́ àìṣòdodo bí, nígbà tí ó bá ń fi ìbínú rẹ̀ hàn? (Mo fi ṣe àkàwé bí ènìyàn.)

[6] Kí a má rí i. Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, Ọlọ́run yóò ha ṣe lè dájọ́ aráyé?

[7] Nítorí bí òtítọ́ Ọlọ́run bá di púpọ̀ sí ìyìn rẹ̀ nítorí èké mi, èéṣe tí a fi ń dá mi lẹ́jọ́ bí ẹlẹ́ṣẹ̀?

[8] Èéṣe tí a kò fi ṣe búburú kí rere lè jáde wá? Bí àwọn kan tí ń fi ẹnu àtẹ́ sọ wí pé a ń sọ bẹ́ẹ̀; ti àwọn kan sì ń tẹnumọ́ ọn pé a sọ; àwọn ẹni tí ìdálẹ́bi wọn tọ́.

[9] Ǹjẹ́ kí ha ni? Àwa ha sàn ju wọn lọ bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá, nítorí a fihàn ṣáájú pé àti àwọn Júù àti àwọn Giriki, gbogbo wọn ni ó wà lábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.

[10] Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Kò sí ẹni tí í ṣe olódodo, kò sí ẹnìkan,

[11] kò sí ẹni tí òye yé, kò sí ẹni tí ó ń wá Ọlọ́run.

[12] Gbogbo wọn ni ó ti yapa, wọ́n jùmọ̀ di aláìlérè; kò sí ẹni tí ń ṣe rere, kò tilẹ̀ sí ẹnìkan.”

[13] “Ibojì tí ó ṣí sílẹ̀ ní ọ̀fun wọn: ahọ́n wọn n sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.” “Oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ lábẹ́ ètè wọn.”

[14] “Ẹnu ẹni tí ó kún fún èpè àti fún oró kíkorò.”

[15] “Ẹsẹ̀ wọn yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀,

[16] ìparun àti ìpọ́njú wà lọ́nà wọn.

[17] Ọ̀nà àlàáfíà ni wọn kò sì mọ̀,”

[18] “Ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò sí níwájú wọn.”

[19] Àwa sì mọ̀ pé ohunkóhun tí òfin bá wí, ó ń wí fún àwọn tí ó wà lábẹ́ òfin: kí gbogbo ẹnu bá à lè dákẹ́ àti kí a lè mú gbogbo aráyé wá sábẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run.

[20] Nítorí pé nípa iṣẹ́ òfin, a kì yóò dá ẹnikẹ́ni láre níwájú rẹ̀: nítorí nípa òfin ni ìmọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ti wá.

[21] Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, a ti fi òdodo Ọlọ́run hàn láìsí òfin, tí a ti ń jẹ́rìí sí nípa òfin àti nípa àwọn wòlíì,

[22] àní òdodo Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi, sí gbogbo ènìyàn àti gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́, nítorí tí kò sí ìyàtọ̀ láàrín Júù àti Helleni.

[23] Gbogbo ènìyàn ni ó ṣá ti ṣẹ̀, tí wọ́n sì kùnà ògo Ọlọ́run,

[24] àwọn ẹni tí a ń dá láre lọ́fẹ̀ẹ́ nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, nípa ìdáǹdè tí ó wà nínú Kristi Jesu.

[25] Ẹni tí Ọlọ́run ti gbé kalẹ̀ láti jẹ́ ètùtù nípa ìgbàgbọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, láti fi òdodo rẹ̀ hàn nítorí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti kọjá, nínú ìpamọ́ra Ọlọ́run,

[26] láti fi òdodo rẹ̀ hàn ní ìgbà ìsinsin yìí: kí ó lè jẹ́ olódodo àti olùdáláre ẹni tí ó gba Jesu gbọ́.

[27] Ọ̀nà ìṣògo dà? A ti mú un kúrò. Nípa òfin wo? Nípa iṣẹ́? Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n nípa òfin ìgbàgbọ́.

[28] Nítorí náà, a parí rẹ̀ sí pé nípa ìgbàgbọ́ ni a ń dá ènìyàn láre láìsí iṣẹ́ òfin.

[29] Ọlọ́run àwọn Júù nìkan ha ni bí? Kì í ha ṣe ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú? Bẹ́ẹ̀ ni, ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú.

[30] Bí ó ti jẹ́ pé Ọlọ́run kan ni, yóò dá àwọn akọlà láre nípa ìgbàgbọ́ àti àwọn aláìkọlà nípa ìgbàgbọ́ wọn.

[31] Àwa ha ń sọ òfin dasán nípa ìgbàgbọ́ bí? Kí a má rí i, ṣùgbọ́n a ń fi òfin múlẹ̀.

Ìwé si àwọn ará Romu — Chapters