Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 3:43

[1] Olúwa sọ fún Mose pé,

[2] “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Tí ẹ bá wọ Kenaani, ilẹ̀ tí a ó fi fún yín, gẹ́gẹ́ bí ogún yín yóò ní ààlà wọn yí:

[3] “ ‘Ìhà gúúsù yín yóò bọ́ sí ara aginjù Sini lẹ́bàá Edomu, àti ìlà-oòrùn, ààlà ìhà gúúsù yóò bẹ̀rẹ̀ láti òpin Òkun Iyọ̀,

[4] kọjá lọ sí gúúsù Akrabbimu, tẹ̀síwájú lọ si Sini, kó bọ́ si gúúsù Kadeṣi-Barnea, kí o sì dé Hasari-Addari, kí o sì kọjá sí Asmoni.

[5] Kí òpin ilẹ̀ rẹ̀ kí ó sì yíká láti Asmoni lọ dé odò Ejibiti, Òkun Ńlá ni yóò sì jẹ òpin rẹ.

[6] Ìhà ìwọ̀-oòrùn yín yóò jẹ́ òpin lórí Òkun Ńlá. Èyí yóò jẹ́ ààlà yín lórí ìhà ìwọ̀-oòrùn.

[7] Fún ààlà ìhà àríwá, fa ìlà láti Òkun Ńlá lọ sí orí òkè Hori,

[8] àti láti orí òkè Hori sí Lebo-Hamati. Nígbà náà ààlà náà yóò lọ sí Sedadi,

[9] tẹ̀síwájú lọ sí Sifroni, kí o sì fò pín si ní Hasari-Enani, èyí yóò jẹ́ ààlà tìrẹ ní ìhà àríwá.

[10] Kí ẹ sì sàmì sí ilẹ̀ tiyín ní ìhà ìlà-oòrùn láti Hasari-Enani lọ dé Ṣefamu.

[11] Ààlà náà yóò ti Ṣefamu sọ̀kalẹ̀ wá lọ sí Ribla ní ìhà ìlà-oòrùn Aini, kí o sì sọ̀kalẹ̀ lọ dé ìhà Òkun Kinnereti ní ìhà ìlà-oòrùn.

[12] Nígbà náà, ààlà náà yóò sọ̀kalẹ̀ lọ sí apá Jordani, yóò sì dópin nínú Òkun Iyọ̀. “ ‘Èyí yóò jẹ́ ilẹ̀ yín, pẹ̀lú ààlà tirẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà.’ ”

[13] Mose pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Yan ilẹ̀ yìí pẹ̀lú kèké gẹ́gẹ́ bí ìní ogún: Olúwa ti pàṣẹ láti fi fún ẹ̀yà mẹ́sàn-án, àti ààbọ̀.

[14] Nítorí ará ilẹ̀ ẹ̀yà ti Reubeni, ẹ̀yà Gadi àti ẹ̀yà ààbọ̀ ti Manase ti gba ogún tiwọn.

[15] Ẹ̀yà méjèèjì àti ààbọ̀ yìí ti gba ogún tiwọn ní ìhà ìhín Jordani létí i Jeriko, ní ìhà ìlà-oòrùn, ní ìdojúkọ Jordani.”

[16] Olúwa sọ fún Mose pé,

[17] “Èyí ni orúkọ àwọn ọkùnrin náà tí yóò pín ilẹ̀, náà fún yín gẹ́gẹ́ bí ogún: Eleasari àlùfáà àti Joṣua ọmọ Nuni.

[18] Kí o sì yan olórí kan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan láti pín ilẹ̀ náà.

[19] “Èyí ni orúkọ wọn: “Kalebu ọmọ Jefunne, láti ẹ̀yà Juda;

[20] Ṣemueli ọmọ Ammihudu, láti ẹ̀yà Simeoni;

[21] Elidadi ọmọ Kisloni, láti ẹ̀yà Benjamini;

[22] Bukki ọmọ Jogli, láti ẹ̀yà olórí àwọn ọmọ Dani;

[23] Hannieli ọmọ Efodu, láti ẹ̀yà Manase, olórí àwọn ọmọ Josẹfu,

[24] Kemueli ọmọ Ṣiftani, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ, Efraimu, ọmọ Josẹfu;

[25] Elisafani ọmọ Parnaki, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Sebuluni;

[26] Paltieli ọmọ Assani, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Isakari;

[27] Ahihudu ọmọ Ṣelomi, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Aṣeri;

[28] Pedaheli ọmọ Ammihudu, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Naftali.”

[29] Èyí ni àwọn ẹni tí Olúwa yàn láti pín ogún náà fún àwọn ọmọ Israẹli ní ilẹ̀ Kenaani.

Ìwé Numeri — Chapters