Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 3:01

[1] Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ nípa Ninefe. Ìwé ìran Nahumu ará Elkoṣi.

[2] Ọlọ́run ń jẹ owú, ó sì ń gbẹ̀san, Olúwa ń gbẹ̀san, ó sì kún fún ìbínú. Olúwa ń gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ìbínú rẹ̀ kò sì yí padà lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.

[3] Olúwa lọ́ra láti bínú, ó sì tóbi ní agbára; Olúwa kì yóò fi àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀ láìjìyà. Ọ̀nà rẹ̀ wà nínú afẹ́fẹ́ àti nínú ìjì, ìkùùkuu sánmọ̀ sì ni eruku ẹsẹ̀ rẹ̀.

[4] Ó bá òkun wí, ó sì mú kí ó gbẹ; Ó sìsọ gbogbo odò di gbígbẹ. Baṣani àti Karmeli sì rọ. Ìtànná Lebanoni sì rẹ̀ sílẹ̀.

[5] Àwọn òkè ńlá wárìrì níwájú rẹ̀, àwọn òkè kéékèèké sì di yíyọ́, ilẹ̀ ayé sì jóná níwájú rẹ̀, àní ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.

[6] Ta ni ó lé dúró níwájú ìbínú rẹ̀? Ta ni ó lé faradà gbígbóná ìbínú rẹ̀? Ìbínú rẹ̀ tú jáde bí iná; àwọn àpáta sì fọ́ túútúú níwájú rẹ̀.

[7] Rere ni Olúwa, òun ni ààbò ní ọjọ́ ìpọ́njú. Òun sì tọ́jú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e,

[8] ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìkún omi ńlá ní òun yóò fi ṣe ìparun láti ibẹ̀ dé òpin; òkùnkùn yóò sì máa lépa àwọn ọ̀tá rẹ̀.

[9] Kí ni ẹ̀yìn ń gbìmọ̀ lòdì sí Olúwa? Òun yóò fi òpin sí i, ìpọ́njú kì yóò wáyé ní ìgbà kejì.

[10] Wọn yóò sì lọ́lù papọ̀ bí ẹ̀gún òṣùṣú wọn yóò sì mu àmupara nínú ọtí wáìnì wọn a ó sì run wọn gẹ́gẹ́ bi àgékù koríko gbígbẹ.

[11] Láti ọ̀dọ̀ rẹ, ìwọ Ninefe, ni ẹnìkan ti jáde wá tí ó ń gbèrò ibi sí Olúwa ti ó sì ń gbìmọ̀ búburú.

[12] Báyìí ni Olúwa wí: “Bí wọ́n tilẹ̀ ni ìfọwọ́sowọ́pọ̀, tí wọ́n sì pọ̀ níye, ṣùgbọ́n, báyìí ní a ó ké wọn lulẹ̀, nígbà tí òun ó bá kọjá. Bí mo tilẹ̀ ti pọ́n ọ lójú ìwọ Juda, èmi kì yóò pọ́n ọ lójúmọ́.

[13] Nísinsin yìí ni èmi yóò já àjàgà wọn kúrò ní ọrùn rẹ èmi yóò já ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ rẹ dànù.”

[14] Olúwa ti fi àṣẹ kan lélẹ̀ nítorí tìrẹ Ninefe: “Ìwọ kì yóò ni irú-ọmọ láti máa jẹ́ orúkọ rẹ mọ́, Èmi yóò pa ère fínfín àti ère dídà run tí ó wà nínú tẹmpili àwọn ọlọ́run rẹ. Èmi yóò wa ibojì rẹ, nítorí ẹ̀gbin ni ìwọ.”

[15] Wò ó, lórí àwọn òkè, àwọn ẹsẹ̀ ẹni tí ó mú ìròyìn ayọ̀ wá, ẹni tí ó ń kéde àlàáfíà. Ìwọ Juda, pa àṣẹ rẹ tí ó ní ìrònú mọ́, kí ó sì san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ. Àwọn ènìyàn búburú kì yóò sì gbóguntì ọ́ mọ́; wọn yóò sì parun pátápátá.

Ìwé Wòlíì Nahumu — Chapters