Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 4:12

[1] Ní ọjọ́ kẹjọ, Mose pe Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn àgbàgbà Israẹli.

[2] Ó sọ fún Aaroni pé, “Mú akọ ọmọ màlúù kan wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti àgbò kan fún ẹbọ sísun, kí méjèèjì jẹ́ aláìlábùkù, kí o sì mú wọn wá sí iwájú Olúwa.

[3] Kí o sì sọ fún àwọn ará Israẹli pé, ‘Ẹ mú òbúkọ kan wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ọmọ màlúù àti ọ̀dọ́-àgùntàn kan, kí méjèèjì jẹ́ ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbùkù fún ẹbọ sísun,

[4] àti akọ màlúù kan àti àgbò kan fún ẹbọ àlàáfíà àti ẹbọ ohun jíjẹ tí a fi òróró pò láti fi rú ẹbọ ní iwájú Olúwa. Nítorí pé Olúwa yóò farahàn yín ní òní.’ ”

[5] Wọ́n kó gbogbo àwọn nǹkan tí Mose pàṣẹ wá sí iwájú àgọ́ ìpàdé, gbogbo ìjọ ènìyàn sì súnmọ́ tòsí, wọ́n sì dúró níwájú Olúwa.

[6] Nígbà náà ni Mose wí pé, “Ohun tí Olúwa pàṣẹ fún yín láti ṣe nìyìí, kí ògo Olúwa bá à lè farahàn yín.”

[7] Mose sọ fún Aaroni pé, “Wá sí ibi pẹpẹ kí o sì rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti ẹbọ sísun rẹ, kí o sì ṣe ètùtù fún ara rẹ àti fún àwọn ènìyàn; rú ẹbọ ti àwọn ènìyàn náà, kí o sì ṣe ètùtù fún wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ.”

[8] Aaroni sì wá sí ibi pẹpẹ, ó pa akọ ọmọ màlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀.

[9] Àwọn ọmọ Aaroni sì mú ẹ̀jẹ̀ náà tọ̀ ọ́ wá, ó sì ti ìka ọwọ́ rẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà, ó fi sí orí ìwo pẹpẹ, ó sì da ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ.

[10] Ó sun ọ̀rá, kíndìnrín àti ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀, èyí tó mú láti inú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, lórí pẹpẹ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mose.

[11] Ó sì sun ara ẹran àti awọ rẹ̀ ní ẹ̀yìn ibùdó.

[12] Lẹ́yìn èyí ó pa ẹran tó wà fún ẹbọ sísun. Àwọn ọmọ Aaroni sì mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, ó sì wọn yí pẹpẹ náà ká.

[13] Wọ́n sì ń mú ẹbọ sísun náà fún un ní ègé kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú orí rẹ̀, ó sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ.

[14] Ó fọ nǹkan inú rẹ̀ àti ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sun wọ́n lórí ẹbọ sísun tó wà lórí pẹpẹ.

[15] Aaroni mú ẹbọ tó jẹ́ ti àwọn ènìyàn wá. Ó mú òbúkọ èyí tó dúró fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn ó sì pa á, ó fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ti àkọ́kọ́.

[16] Ó mú ẹbọ sísun wá, ó sì rú u gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí a fi lélẹ̀.

[17] Ó tún mu ẹbọ ohun jíjẹ wá, ó bu ẹ̀kúnwọ́ kan nínú rẹ̀, ó sì sun ún lórí pẹpẹ ní àfikún ẹbọ sísun tí àárọ̀.

[18] Ó pa akọ màlúù àti àgbò bí ẹbọ àlàáfíà fún àwọn ènìyàn. Àwọn ọmọ Aaroni sì mú ẹ̀jẹ̀ ẹran náà tọ̀ ọ́ wá, ó sì wọn yí pẹpẹ náà ká.

[19] Ṣùgbọ́n ọ̀rá akọ màlúù àti àgbò náà: ìrù rẹ̀ tí ó lọ́ràá, básí ọ̀rá, ọ̀rá kíndìnrín, àti ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀:

[20] gbogbo rẹ̀ ni wọ́n kó lórí igẹ̀ ẹran náà. Aaroni sì sun ọ̀rá náà lórí pẹpẹ.

[21] Aaroni fi igẹ̀ àti itan ọ̀tún ẹran náà níwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì bí Mose ṣe pa á láṣẹ.

[22] Aaroni sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí àwọn ènìyàn, ó sì súre fún wọn. Lẹ́yìn tó sì ti rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ẹbọ sísun àti ẹbọ àlàáfíà, ó sọ̀kalẹ̀.

[23] Mose àti Aaroni sì wọ inú àgọ́ ìpàdé. Nígbà tí wọ́n jáde, wọ́n súre fún àwọn ènìyàn, ògo Olúwa sì farahàn sí gbogbo ènìyàn.

[24] Iná sì jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ó sì jó ẹbọ sísun àti ọ̀rá orí pẹpẹ. Nígbà tí gbogbo ènìyàn sì rí èyí wọ́n hó ìhó ayọ̀, wọ́n sì dojúbolẹ̀.

Ìwé Lefitiku — Chapters