Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 3:28

[1] Àsọtẹ́lẹ̀ tí wòlíì Habakuku rí.

[2] Olúwa, èmi yóò ti ké pẹ́ tó fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n ti ìwọ kò ni fetí sí mi? Tàbí kígbe sí ọ ní ti, “Ìwà ipá!” Ṣùgbọ́n tí ìwọ kò sì gbàlà?

[3] Èéṣe tí ìwọ fi mú mi rí àìṣedéédéé? Èéṣe tí ìwọ sì fi ààyè gba ìwà ìkà? Ìparun àti ìwà ipá wà ní iwájú mi; ìjà ń bẹ, ìkọlù sì wà pẹ̀lú.

[4] Nítorí náà, òfin di ohun àìkàsí, ìdájọ́ òdodo kò sì borí. Àwọn ẹni búburú yí àwọn olódodo ká, nítorí náà ni ìdájọ́ òdodo ṣe yí padà.

[5] “Ẹ wo inú àwọn kèfèrí, ki ẹ sí wòye, kí háà kí ó sì ṣe yin gidigidi. Nítorí èmi ó ṣe ohun kan ní ọjọ́ yín tí ẹ̀yin kò jẹ́ gbàgbọ́, bí a tilẹ̀ sọ fún yin.

[6] Nítorí pé, èmi yóò gbé àwọn ara Babeli dìde, àwọn aláìláàánú àti onínú-fùfù ènìyàn tí ó rin gbogbo ilẹ̀ ayé já láti fi agbára gbà àwọn ibùgbé tí kì í ṣe tiwọn.

[7] Wọn jẹ́ ènìyàn ti a bẹ̀rù, tí a sì páyà, ìdájọ́ wọn, àti ọláńlá wọn, yóò máa ti inú wọn jáde.

[8] Ẹṣin wọn yára ju ẹkùn lọ, wọ́n sì gbóná jú ìkookò àṣálẹ́ lọ àwọn ẹlẹ́ṣin wọn yóò sí tan ara wọn ká; wọn yóò sì wá láti ọ̀nà jíjìn réré, wọn yóò sí fò bí ẹyẹ igún tí ń wá láti jẹrun,

[9] gbogbo wọn sì wà fún ìwà ipá ìwò ojú wọn yóò sì wá síwájú; wọn sì ko ìgbèkùn jọ bí iyanrìn.

[10] Wọn ó si máa fi àwọn ọba ṣẹ̀sín wọn ó sì tún kẹ́gàn àwọn aládé. Wọn yóò sì fi gbogbo ìlú odi alágbára nì rẹ́rìn-ín; nítorí pé, wọn yóò ko erùpẹ̀ jọ, wọn yóò sì gbà á.

[11] Nígbà náà ni inú rẹ̀ yóò yípadà, yóò sì rékọjá, yóò si ṣẹ̀ ní kíka agbára rẹ̀ yìí sí iṣẹ́ òrìṣà rẹ̀.”

[12] Olúwa, ǹjẹ́ láti ayérayé kọ ni ìwọ tí wà? Olúwa Ọlọ́run mi. Ẹni mímọ́ mi, àwa kì yóò kú Olúwa, ìwọ tí yàn wọn fún ìdájọ́; Ọlọ́run alágbára, ìwọ tí fi ẹsẹ̀ wọn múlẹ̀ fún ìbáwí.

[13] Ojú rẹ mọ́ tónítóní láti wo ibi; ìwọ kò le gbà ìwà ìkà nítorí kí ni ìwọ ṣe gba àwọn alárékérekè láààyè? Nítorí kí ni ìwọ ṣe dákẹ́ nígbà tí ẹni búburú ń pa ẹni tí i ṣe olódodo ju wọn lọ run?

[14] Ìwọ sì tí sọ ènìyàn di bí ẹja inú Òkun, bí ohun tí ń rákò tí wọn ko ni alákòóso.

[15] Àwọn ènìyàn búburú fi àwọ̀n wọn gbé wọn sókè ó sì kó wọn jọ nínú àwọ̀n ńlá rẹ̀; nítorí náà, ó dunnú, ó sì yọ̀ pẹ̀lú.

[16] Nítorí náà, ó rú ẹbọ sí àwọ̀n rẹ̀, ó sì ń sun tùràrí fún àwọ̀n ńlá rẹ̀ nítorí pẹ̀lú àwọ̀n rẹ̀ ni ó fi ń gbé ní ìgbádùn tí ó sì ń gbádùn pẹ̀lú oúnjẹ tí ó bá wù ú.

[17] Ǹjẹ́ wọn yóò ha máa pa àwọ̀n wọn mọ́ ní òfìfo bí, tí wọn yóò sì pa orílẹ̀-èdè run láìsí àánú?

Ìwé Wòlíì Habakuku — Chapters