Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 3:01

[1] Ará, bí a tilẹ̀ mú ènìyàn nínú ẹ̀ṣẹ̀ kan, kí ẹ̀yin tí í ṣe ti Ẹ̀mí mú irú ẹni bẹ́ẹ̀ bọ̀ sípò nínú ẹ̀mí ìwà tútù; kí ìwọ tìkára rẹ̀ máa kíyèsára, kí a má ba à dán ìwọ náà wò pẹ̀lú.

[2] Ẹ máa ru ẹrù ọmọnìkejì yín, kí ẹ sì fi bẹ́ẹ̀ mú òfin Kristi ṣẹ.

[3] Nítorí bí ènìyàn kan bá ń ro ara rẹ̀ sí ẹnìkan, nígbà tí kò jẹ́ nǹkan, ó ń tan ara rẹ̀ jẹ.

[4] Ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù yẹ iṣẹ́ ara rẹ̀ wò, nígbà náà, ohun ìmú-ṣogo rẹ̀ yóò jẹ́ nínú ti ara rẹ̀ nìkan, kì yóò sì jẹ nínú ti ọmọnìkejì rẹ̀.

[5] Nítorí pé olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ara rẹ̀.

[6] Ṣùgbọ́n kí ẹni tí a ń kọ́ nínú ọ̀rọ̀ náà máa pèsè ohun rere gbogbo fún ẹni tí ń kọ́ni.

[7] Kí a má ṣe tàn yín jẹ; a kò lè gan Ọlọ́run: nítorí ohunkóhun tí ènìyàn bá fúnrúgbìn, òhun ni yóò sì ká.

[8] Nítorí ẹni tí ó bá ń fúnrúgbìn sípa ti ara yóò ká ìdíbàjẹ́ ti ara ṣùgbọ́n ẹni tí ń fúnrúgbìn sípa ti ẹ̀mí yóò ti inú ẹ̀mí ká ìyè àìnípẹ̀kun.

[9] Ẹ má sì jẹ́ kí àárẹ̀ ọkàn mú wa ní ṣíṣe rere, nítorí tí a ó kórè nígbà tí àkókò bá dé, bí a kò bá ṣe àárẹ̀.

[10] Ǹjẹ́ bí a ti ń rí àǹfààní gba, ẹ jẹ́ kí a máa ṣoore fún gbogbo ènìyàn, àti pàápàá fún àwọn tí í ṣe ará ilé ìgbàgbọ́.

[11] Ẹ wo bí mo ti fi ọwọ́ ara mi kọ̀wé gàdàgbà-gàdàgbà sí yín.

[12] Iye àwọn tí ń fẹ́ ṣe àṣehàn ni ara wọn ń rọ yín láti kọlà; kìkì nítorí pé kí a má ba à ṣe inúnibíni sí wọn nítorí àgbélébùú Kristi.

[13] Nítorí àwọn tí a kọ ní ilà pàápàá kò pa òfin mọ́, ṣùgbọ́n wọ́n ń fẹ́ mú yin kọlà, kí wọn lè máa ṣògo nínú ara yín.

[14] Ṣùgbọ́n kí a má ṣe rí i pé èmi ń ṣògo, bí kò ṣe nínú àgbélébùú Jesu Kristi Olúwa wa, nípasẹ̀ ẹni tí a ti kan ayé mọ́ àgbélébùú fún mi, àti èmi fún ayé.

[15] Nítorí pé nínú Kristi Jesu, ìkọlà kò jẹ́ ohun kan, tàbí àìkọlà, bí kò ṣe ẹ̀dá tuntun.

[16] Kí àlàáfíà àti àánú wà lórí gbogbo àwọn tí ń rìn ní ìlànà yìí, àti lórí Israẹli Ọlọ́run.

[17] Láti ìsinsin yìí lọ, kí ẹnikẹ́ni má ṣe yọ mí lẹ́nu mọ́; nítorí èmi ń ru àpá Jesu Olúwa kiri ní ara mi.

[18] Ará, oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa, kí ó wà pẹ̀lú ẹ̀mí yín. Àmín.

Ìwé sí àwọn ará Galatia — Chapters