[1] Lẹ́yìn ikú Ahabu, Moabu ṣọ̀tẹ̀ sí Israẹli.
[2] Nísinsin yìí Ahasiah ti ṣubú láàrín fèrèsé láti òkè yàrá rẹ̀ tí ó wà ní Samaria, ó sì fi ara pa. Ó sì rán oníṣẹ́, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Baali-Sebubu, òrìṣà Ekroni, bóyá èmi ó lè rí ìwòsàn ìfarapa yìí.”
[3] Ṣùgbọ́n angẹli Olúwa wí fún Elijah ará Tiṣibi pé, “Lọ sókè kí o lọ bá ìránṣẹ́ ọba Samaria kí o sì béèrè lọ́wọ́ wọn, ‘Ṣé nítorí pé kò sí Ọlọ́run ní Israẹli ni ẹ̀yìn fi jáde lọ ṣèwádìí lọ́wọ́ Baali-Sebubu òrìṣà Ekroni?’
[4] Nítorí náà ohun tí Olúwa sọ ní èyí, ‘Ìwọ kò ní kúrò lórí ibùsùn tí o dùbúlẹ̀ lé. Dájúdájú ìwọ yóò kú!’ ” Bẹ́ẹ̀ ni Elijah lọ.
[5] Nígbà tí ìránṣẹ́ náà padà sí ọ̀dọ̀ ọba, ó béèrè ní ọwọ́ wọn pé, “Kí ni ó dé tí ẹ̀yin fi tètè padà wá?”
[6] Wọ́n dáhùn pé, “Ọkùnrin kan wá láti pàdé wa, ó sì wí fún wa pé, ‘Ẹ padà sí ọ̀dọ̀ ọba tí ó rán an yín kí ẹ sì wí fún un pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Ṣé nítorí wí pé kò sí Ọlọ́run ní Israẹli ni o fi ń rán àwọn ènìyàn láti lọ ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Baali-Sebubu, òrìṣà Ekroni? Nítorí náà ìwọ kò ní fi orí ibùsùn tí ìwọ dùbúlẹ̀ lé sílẹ̀. Láìsí àní àní ìwọ yóò kùú!” ’ ”
[7] Ọba béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Irú ọkùnrin wo ni ó wá pàdé yín, tí ó sì sọ irú èyí fún un yín?”
[8] Wọ́n dáhùn pé, “Ó jẹ́ ọkùnrin tí ó wọ ẹ̀wù onírun lára pẹ̀lú ọ̀já àmùrè aláwọ tí ó gbà yíká ìbàdí rẹ̀.” Ọba sì wí pé, “Elijah ará Tiṣibi ni.”
[9] Ó sì rán balógun pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ogun àádọ́ta rẹ̀. Balógun náà sì gòkè tọ Elijah lọ, ẹni tí ó jókòó ní orí òkè, wọ́n sì wí fún un pé, “Ènìyàn Ọlọ́run, ọba wí pé, ‘Sọ̀kalẹ̀ wá!’ ”
[10] Elijah sì dá balógun lóhùn pé, “Tí ó bá jẹ́ wí pé ènìyàn Ọlọ́run ni mí, kí iná kí ó sọ̀kalẹ̀ láti òkè ọ̀run wá kí ó sì jó ìwọ àti àwọn àádọ́ta ọkùnrin rẹ!” Nígbà náà iná náà sì sọ̀kalẹ̀ wá láti òkè ọ̀run ó sì jó balógun àti àwọn ènìyàn rẹ̀.
[11] Ọba sì tún rán balógun àádọ́ta pẹ̀lú àwọn ènìyàn àádọ́ta rẹ̀ sí Elijah. Balógun náà sì wí fún un pé, “Ènìyàn Ọlọ́run, èyí ni ohun tí ọba sọ, ‘Sọ̀kalẹ̀ kánkán!’ ”
[12] “Tí èmi bá jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run,” Elijah sì dáhùn, “Ǹjẹ́ kí iná kí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run kí ó sì jó ọ run àti àwọn àádọ́ta ènìyàn rẹ!” Nígbà náà iná Ọlọ́run sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run ó sì jó o run pẹ̀lú àwọn àádọ́ta ènìyàn rẹ̀.
[13] Bẹ́ẹ̀ ni ọba tún rán balógun kẹta pẹ̀lú àwọn àádọ́ta ọkùnrin. Balógun ẹ̀ẹ̀kẹ́ta lọ sí òkè, ó sì kúnlẹ̀ lórí orókún rẹ̀ níwájú Elijah. “Ènìyàn Ọlọ́run,” Ó sì bẹ̀bẹ̀ pé, “Ìwọ ènìyàn Ọlọ́run, jọ̀wọ́ jẹ́ kí ẹ̀mí mi àti ẹ̀mí àwọn àádọ́ta ìránṣẹ́ rẹ wọ̀nyí ṣọ̀wọ́n ní ojú rẹ!
[14] Wò ó, iná ti sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run láti jó àwọn balógun méjì àràádọ́ta àkọ́kọ́ pẹ̀lú àràádọ́ta wọn. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ní ojúrere fún ẹ̀mí mi!”
[15] Angẹli Olúwa sọ fún Elijah pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú rẹ̀; má ṣe bẹ̀rù rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni Elijah dìde ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ ọba.
[16] Ó sọ fún ọba pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí, ‘Ṣé nítorí wí pé kò sí Ọlọ́run ní Israẹli fún ọ láti pè ni ìwọ fi rán ìránṣẹ́ lọ sí ọ̀dọ̀ Baali-Sebubu, òrìṣà Ekroni láti lọ ṣe ìwádìí?’ Nítorí pé o ṣe èyí, ìwọ kò ní dìde lórí ibùsùn tí o dùbúlẹ̀ lé láìsí àní àní ìwọ yóò kú!”
[17] Bẹ́ẹ̀ ó sì kú, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí Elijah ti sọ. Nítorí Ahasiah kò ní ọmọ, Jehoramu jẹ ọba ní ọdún kejì tí Jehoramu ọmọ Jehoṣafati ọba Juda.
[18] Àti ní ti gbogbo àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà ìjọba Ahasiah, àti ohun tí ó ṣe, ṣe a kò ha kọ wọ́n sí inú ìwé ọdọọdún ti àwọn ọba Israẹli?