Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 2:15

[1] Alàgbà, Sì àyànfẹ́ obìnrin ọlọ́lá àti àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn tí mo fẹ́ ní òtítọ́, kì í sì í ṣe èmi nìkan, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí ó mọ òtítọ́ pẹ̀lú;

[2] nítorí òtítọ́ tí ń gbé inú wa, yóò sì bá wa gbé títí:

[3] Oore-ọ̀fẹ́, àánú, àti àlàáfíà, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba, àti láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, Ọmọ Baba, yóò wà pẹ̀lú wa nínú òtítọ́ àti nínú ìfẹ́.

[4] Mo yọ̀ gidigidi pé mo rí nínú àwọn ọmọ rẹ tí ń rìn nínú òtítọ́, gẹ́gẹ́ bí Baba ti pa àṣẹ fún wa.

[5] Ǹjẹ́ nísinsin yìí, mo bẹ̀ ọ́, obìnrin ọlọ́lá, kì í ṣe bí ẹni pé èmi ń kọ̀wé òfin tuntun kan sí ọ, bí kò ṣe èyí ti àwa tí ní ní àtètèkọ́ṣe, pé kí àwa fẹ́ràn ara wa.

[6] Èyí sì ni ìfẹ́, pé, kí àwa máa rin nípa òfin rẹ̀, èyí ni òfin náà, àní bí ẹ ti gbọ́ ni àtètèkọ́ṣe, pé, kí ẹ̀yin rìn nínú rẹ̀.

[7] Nítorí ẹlẹ́tàn púpọ̀ ti jáde wa sínú ayé, àwọn tí kò jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wá nínú ara. Èyí ni ẹlẹ́tàn àti aṣòdì sí Kristi.

[8] Ẹ kíyèsára yín, kí ẹ má ba à sọ iṣẹ́ tí ẹ tí ṣe nù, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè rí èrè kíkún gbà.

[9] Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń rú òfin tí kò si dúró nínú ẹ̀kọ́ Kristi, kò mọ Ọlọ́run. Ẹni tí ó bá dúró nínú ẹ̀kọ́, òun ni ó mọ Baba àti Ọmọ.

[10] Bí ẹnikẹ́ni bá tọ̀ yín wá, tí kò sì mu ẹ̀kọ́ yìí wá, ẹ má ṣe gbà á sí ilé, kí ẹ má sì ṣe kí i kú ààbọ̀.

[11] Nítorí ẹni tí ó bá kí kú ààbọ̀, ó ní ọwọ́ nínú iṣẹ́ búburú rẹ̀.

[12] Bí mo tilẹ̀ ní ohun púpọ̀ láti ṣe alábápín pẹ̀lú yín, síbẹ̀ èmi kò fẹ́ lo ìwé ìkọ̀wé àti jẹ́lú ìkọ̀wé. Ṣùgbọ́n èmi ní ìrètí láti tọ̀ yín wá àti láti bá a yín sọ̀rọ̀ lójúkojú, kí ayọ̀ yín bá à le è kún.

[13] Àwọn ọmọ arábìnrin rẹ àyànfẹ́ kí ọ.