Skip to content
Opens in a new window
Listen to this chapter • 5:59

[1] Hesekiah sì ránṣẹ́ sí gbogbo Israẹli àti Juda, ó sì kọ ìwé sí Efraimu àti Manase, kí wọn kí ó wá sínú ilé Olúwa ní Jerusalẹmu láti pa àjọ ìrékọjá mọ́ sí Olúwa Ọlọ́run Israẹli.

[2] Nítorí tí ọba ti gbìmọ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀, àti gbogbo ìjọ ènìyàn ní Jerusalẹmu, láti pa àjọ ìrékọjá mọ́ ní oṣù kejì.

[3] Nítorí wọn kò lè pa á mọ́ ní àkókò náà, nítorí àwọn àlùfáà kò tí i ya ara wọn sí mímọ́ tó; bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kò tí ì kó ara wọn jọ sí Jerusalẹmu.

[4] Ọ̀rọ̀ náà sí tọ́ lójú ọba àti lójú gbogbo ìjọ ènìyàn.

[5] Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi àṣẹ kan lélẹ̀, láti kéde ká gbogbo Israẹli láti Beerṣeba àní títí dé Dani, láti wá pa àjọ ìrékọjá mọ́ sí Olúwa Ọlọ́run Israẹli ní Jerusalẹmu: nítorí wọn kò pa á mọ́ ní ọjọ́ púpọ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́.

[6] Bẹ́ẹ̀ àwọn oníṣẹ́ tí ń sáré lọ pẹ̀lú ìwé láti ọwọ́ ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀ sí gbogbo Israẹli àti Juda; àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba, wí pé, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli ẹ yí padà sí Olúwa Ọlọ́run Abrahamu, Isaaki, àti Israẹli, òun ó sì yípadà sí àwọn ìyókù nínú yín, tí ó sálà kúrò lọ́wọ́ àwọn ọba Asiria.

[7] Kí ẹ̀yin kí ó má sì ṣe dàbí àwọn baba yín, àti bí àwọn arákùnrin yín tí ó dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wọn, nítorí náà ní ó ṣe fi wọ́n fún ìdahoro bí ẹ̀yin ti rí.

[8] Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin kí ó má ṣe ṣe ọlọ́rùn líle, bí àwọn baba yín, ṣùgbọ́n ẹ jọ̀wọ́ ara yín lọ́wọ́ fún Olúwa, kí ẹ sì wọ inú ibi mímọ́ rẹ̀ lọ, ti òun ti ìyàsímímọ́ títí láé. Kí ẹ sì sin Olúwa, Ọlọ́run yín kí gbígbóná ìbínú rẹ̀ kí ó lè yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ yín.

[9] Nítorí bí ẹ̀yin bá tún yípadà sí Olúwa, àwọn arákùnrin yín, àti àwọn ọmọ yín, yóò rí àánú níwájú àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ, kí wọn kí ó lè tún padà wá sí ilẹ̀ yí: nítorí Olúwa Ọlọ́run yín, oníyọnu àti aláàánú ni, kì yóò sì yí ojú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ yín, bí ẹ̀yin bá padà sọ́dọ̀ rẹ̀.”

[10] Bẹ́ẹ̀ ni àwọn oníṣẹ́ náà kọjá láti ìlú dé ìlú, ní ilẹ̀ Efraimu àti Manase títí dé Sebuluni, ṣùgbọ́n wọ́n fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà, wọ́n sì gàn wọ́n.

[11] Síbẹ̀ òmíràn nínú àwọn ènìyàn Aṣeri àti Manase àti Sebuluni rẹ̀ ara wọn sílẹ̀, wọ́n sì wá sí Jerusalẹmu.

[12] Ní Juda pẹ̀lú, ọwọ́ Ọlọ́run wá láti fún wọn ní ọkàn kan láti pa òfin ọba mọ́ àti tí àwọn ìjòyè, nípa ọ̀rọ̀ Olúwa.

[13] Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì péjọ ní Jerusalẹmu, láti pa àjọ àkàrà àìwú mọ́ ní oṣù kejì.

[14] Wọ́n sì dìde, wọ́n sì kó gbogbo pẹpẹ tí ó wà ní Jerusalẹmu lọ, àti gbogbo pẹpẹ tùràrí ni wọ́n kó lọ, wọ́n sì dà wọ́n sí odò Kidironi.

[15] Nígbà náà ni wọ́n pa ẹran ìrékọjá náà ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kejì: ojú sì ti àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, wọ́n sì yà ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì mú ẹbọ sísun wá sínú ilé Olúwa.

[16] Wọ́n sì dúró ní ipò wọn, bí ètò wọn gẹ́gẹ́ bí òfin Mose, ènìyàn Ọlọ́run: àwọn àlùfáà wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà, tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Lefi.

[17] Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó wà nínú ìjọ ènìyàn náà tí kò yà ara wọn sí mímọ́: nítorí náà ni àwọn ọmọ Lefi ṣe ń tọ́jú àti pa ẹran ìrékọjá fún olúkúlùkù ẹni tí ó ṣe aláìmọ́, láti yà á sí mímọ́ sí Olúwa.

[18] Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú Efraimu àti Manase, Isakari, àti Sebuluni kò sá wẹ̀ ara wọn mọ́ síbẹ̀ wọ́n jẹ ìrékọjá náà, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́. Ṣùgbọ́n Hesekiah bẹ̀bẹ̀ fún wọn, wí pé, Olúwa, ẹni rere, dáríjì olúkúlùkù,

[19] tí ó múra ọkàn rẹ̀ láti wá Ọlọ́run, Olúwa Ọlọ́run àwọn baba rẹ̀ ṣùgbọ́n tí kì í ṣe nípa ìwẹ̀nùmọ́ mímọ́

[20] Olúwa sì gbọ́ ti Hesekiah, ó sì mú àwọn ènìyàn náà láradá.

[21] Àwọn ọmọ Israẹli tí a rí ní Jerusalẹmu fi ayọ̀ ńlá pa àjọ àkàrà àìwú mọ́ ní ọjọ́ méje: àwọn ọmọ Lefi, àti àwọn àlùfáà yin Olúwa lójoojúmọ́, wọ́n ń fi ohun èlò olóhùn gooro kọrin sí Olúwa.

[22] Hesekiah sọ̀rọ̀ ìtùnú fún gbogbo àwọn ọmọ Lefi, tí ó lóye ní ìmọ̀ rere Olúwa: ọjọ́ méje ni wọ́n fi jẹ àsè náà wọ́n rú ẹbọ àlàáfíà, wọ́n sì ń fi ohùn rara dúpẹ́ fún Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wọn.

[23] Gbogbo ìjọ náà sì gbìmọ̀ láti pa ọjọ́ méje mìíràn mọ́: wọ́n sì fi ayọ̀ pa ọjọ́ méje mìíràn mọ́.

[24] Nítorí Hesekiah, ọba Juda, ta ìjọ ènìyàn náà ní ọrẹ, ẹgbẹ̀rún (1,000) akọ màlúù, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) àgùntàn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn àlùfáà sì ya ara wọn sí mímọ́.

[25] Gbogbo ìjọ ènìyàn Juda pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, àti gbogbo ìjọ ènìyàn tí ó ti inú Israẹli jáde wá, àti àwọn àjèjì tí ó ti ilẹ̀ Israẹli jáde wá, àti àwọn tí ń gbé Juda yọ̀.

[26] Bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ ńlá sì wà ní Jerusalẹmu: nítorí láti ọjọ́ Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli, irú èyí kò sí ní Jerusalẹmu.

[27] Nígbà náà ni àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi dìde, wọ́n sì súre fún àwọn ènìyàn náà: a sì gbọ́ ohùn wọn, àdúrà wọn sì gòkè lọ si ibùgbé mímọ́ rẹ̀, àní sí ọ̀run.

Ìwé Kronika Kejì — Chapters