[1] Solomoni ọba sì jẹ ọba lórí gbogbo Israẹli.
[2] Àwọn wọ̀nyí sì ni ìjòyè rẹ̀: Asariah ọmọ Sadoku àlùfáà:
[3] Elihorefu àti Ahijah àwọn ọmọ Ṣisa akọ̀wé; Jehoṣafati ọmọ Ahiludi ni akọ̀wé ìlú;
[4] Benaiah ọmọ Jehoiada ni olórí ogun; Sadoku àti Abiatari ni àwọn àlùfáà;
[5] Asariah ọmọ Natani ni olórí àwọn agbègbè; Sabudu ọmọ Natani, àlùfáà àti olùgba ọba ní ìmọ̀ràn;
[6] Ahiṣari ni olùtọ́jú ààfin; Adoniramu ọmọ Abida ni ó ń ṣe olórí iṣẹ́-ìlú.
[7] Solomoni sì tún ní ìjòyè méjìlá lórí gbogbo agbègbè Israẹli, tí wọ́n ń pèsè oúnjẹ fún ọba àti agbo ilé rẹ̀. Olúkúlùkù ní láti pèsè fún oṣù kan ní ọdún.
[8] Orúkọ wọn ni wọ̀nyí: Bene-Huri ní ìlú olókè Efraimu.
[9] Bene-Dekeri ní Makasi, Ṣaalbimu, Beti-Ṣemeṣi, àti Eloni Beti-Hanani;
[10] Bene-Hesedi, ní Aruboti (tirẹ̀ ni Soko àti gbogbo ilẹ̀ Heferi ń ṣe);
[11] Bene-Abinadabu, ní Napoti (Dori; òun ni ó fẹ́ Tafati ọmọbìnrin Solomoni ní aya).
[12] Baana ọmọ Ahiludi, ní Taanaki àti Megido, àti ní gbogbo Beti-Ṣeani tí ń bẹ níhà Saretani ní ìsàlẹ̀ Jesreeli, láti Beti-Ṣeani dé Abeli-Mehola títí dé ibi tí ń bẹ ní ìkọjá Jokimeamu.
[13] Ọmọ Geberi ní Ramoti Gileadi (tirẹ̀ ni àwọn ìletò Jairi ọmọ Manase tí ń bẹ ní Gileadi, tirẹ̀ sì ni agbègbè Argobu, tí ń bẹ ní Baṣani, ọgọ́ta ìlú tí ó tóbi pẹ̀lú odi tí ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ irin).
[14] Ahinadabu ọmọ Iddo ní Mahanaimu
[15] Ahimasi ní Naftali (ó fẹ́ Basemati ọmọbìnrin Solomoni ní aya).
[16] Baana ọmọ Huṣai ní Aṣeri àti ní Aloti;
[17] Jehoṣafati ọmọ Parua ni ó wà ní Isakari;
[18] Ṣimei ọmọ Ela ni Benjamini;
[19] Geberi ọmọ Uri ní Gileadi (orílẹ̀-èdè Sihoni ọba àwọn ará Amori àti orílẹ̀-èdè Ogu ọba Baṣani). Òun nìkan ni ìjòyè lórí ilẹ̀ náà.
[20] Àwọn ènìyàn Juda àti ti Israẹli pọ̀ gẹ́gẹ́ bí iyanrìn tí ń bẹ ní etí Òkun; wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, wọ́n sì ń yọ ayọ̀.
[21] Solomoni sì ń ṣàkóso lórí gbogbo àwọn ìjọba láti odò Eufurate títí dé ilẹ̀ àwọn ará Filistini, àti títí dé etí ilẹ̀ Ejibiti. Àwọn orílẹ̀-èdè yìí ń mú owó òde wá, wọ́n sì ń sin Solomoni ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.
[22] Oúnjẹ Solomoni fún ọjọ́ kan jásí ọgbọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná àti ọgọ́ta òsùwọ̀n ìyẹ̀fun,
[23] Màlúù mẹ́wàá tí ó sanra, àti ogún màlúù láti inú pápá wá, àti ọgọ́rùn-ún àgùntàn àti ewúrẹ́, láìka àgbọ̀nrín àti èsúró, àti ogbúgbu, àti ẹyẹ tí ó sanra.
[24] Nítorí òun ni ó ṣàkóso lórí gbogbo agbègbè ní ìhà ìwọ̀-oòrùn odò Eufurate, láti Tifisa títí dé Gasa, lórí gbogbo àwọn ọba ní ìhà ìhín odò, ó sì ní àlàáfíà ní gbogbo ìlú tí ó yí i káàkiri.
[25] Nígbà ayé Solomoni, Juda àti Israẹli, láti Dani títí dé Beerṣeba, wọ́n ń gbé ní àlàáfíà, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀.
[26] Solomoni sì ní ẹgbàajì (4,000) ilé ẹṣin fún kẹ̀kẹ́ rẹ̀, àti ẹgbàá mẹ́fà (12,000) ẹlẹ́ṣin.
[27] Àwọn ìjòyè agbègbè, olúkúlùkù ní oṣù rẹ̀, ń pèsè oúnjẹ fún Solomoni ọba àti gbogbo àwọn tí ń wá sí ibi tábìlì ọba, wọ́n sì rí i pé ohun kankan kò ṣẹ́kù.
[28] Wọ́n tún máa ń mú ọkà barle àti koríko fún ẹṣin àti fún ẹṣin sísáré wá pẹ̀lú sí ibi tí ó yẹ, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí ìlànà tirẹ̀.
[29] Ọlọ́run sì fún Solomoni ní ọgbọ́n, àti òye ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, àti ìmọ̀ gbígbòòrò òye tí a kò le è fiwé iyanrìn tí ó wà létí Òkun.
[30] Ọgbọ́n Solomoni sì pọ̀ ju ọgbọ́n ọkùnrin ìlà-oòrùn lọ, ó sì pọ̀ ju gbogbo ọgbọ́n Ejibiti lọ.
[31] Ó sì ní òye ju gbogbo ènìyàn lọ, ju Etani, ará Esra, àti Hemani àti Kalkoli, àti Darda àwọn ọmọ Maholi lọ. Òkìkí rẹ̀ sì kàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè yíká.
[32] Ó sì pa ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) òwe, àwọn orin rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó lé márùn-ún (1,005).
[33] Ó sì sọ̀rọ̀ ti igi, láti kedari tí ń bẹ ní Lebanoni dé Hísópù tí ń dàgbà lára ògiri. Ó sì tún sọ ti àwọn ẹranko àti ti àwọn ẹyẹ, àti ohun tí ń rákò àti ti ẹja.
[34] Àwọn ènìyàn sì ń wá láti gbogbo orílẹ̀-èdè láti gbọ́ ọgbọ́n Solomoni, láti ọ̀dọ̀ àwọn ọba ayé láti wá gbọ́ nípa ọgbọ́n rẹ̀.